Won
ni ojo gbogbo ni ti ole, ojo kan soso ni ti olohun, eyi lo nibamu pelu bowo
olopaa ZIS, iyen Zonal Intervention Squad to wa niluu Abeokuta nipinle Ogun
State se te awon ore meta kan ni won so pe won ko nise meji ju ki won fi moto
lu awon araalu nijibi owo atawon nkan min in.
Seun Ademosu, Segun Akinde ati Kayode
Sokunbi la gbo pe asiri won tu lagbegbe Itori nijoba ibile Ewekoro lawon eeyan
naa ti won so pe won lu obinrin kan, Kehinde Oluwaferanmi ni jibiti egberun
lona ogorun naira, ti won si fogbon le e bo sile ninu moto lojo kejila osu to
koja.
Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni se ni se
lawon meteeta naa n fi moto won sise buruku naa, ti won a si dogbon bii pe won
ko mo ara won ri nigba ti won ba gbe eni ti ba fe e lu ni jibiti, igba ti won
ba sise ibi naa tan ni won maa dogbon bii eni pe moto baje, tabi wi pe ilekun
mu eni kan lowo, ti won a si fibinu le eni ti won ba ti sise ibi naa lara bo
sile.
Bayii ni won se fun Kehinde lojo naa,
to je pe leyin ti won lo tan loun naa too fura wi pe won ti pa idan lara oun,
ko too gba tesan olopaa ZIS lo lati loo fi to won leti.
Lojo naa la gbo pe owo te Segun ati
Kayode, ti won si jewo pe Seun gangan ni olori won, sugbon to ti na papa bora,
tawon olopaa naa ko si da ise duro lati rii mu.
Nigba ti won lori maa tako Seun, okan
lara awon onisowo simenti la gbo pe o tun lu ni jibiti owo to to milionu kan
aabo (1.4) naira, eni ti won so pe Ifo lo n ti n bo, to fe e lo san owo si
Banki kan l'Ewekoro.
AWIKONKO gbo pe nigba ti won de agbegbe
kan ti won pe ni Abule Oko ni won tun dogbon wi pe ilekun mu eni kan lowo tawon
ti won jo n sise naa si so fun awako, iyen Seun wi pe ko duro.
Bi Seun se paaki moto e segbe kan, ti
won n se bi eni to fe e bo sile, ni won ba ja baagi obinrin naa gba, ti won tii
bo sile ninu moto, ti won si salo.
Leyin ojo keta la gbo pe obinrin naa
too tun pada foju kan Seun lakoko to tun n gbiyanju lati sise buruku naa pelu
awon ti won jo n se e, to si pariwo le e lori, ko too di pe awon to wa nibe
muu.
Iyalenu lo je pe bi won se n mu Seun wo
tesan olopaa lawon ore e meji towo ti koko te pariwo e pe olori won gangan to
salo niyen.
Ohun ta a gbo pe o je kayeefi ni bi
Seun, eni odun mejidinlogbon (28) se so pe oun ko mo nkankan nipa esun ti won
fi kan oun, nitori pe tori koun ma baa jale loun se n fi moto naa sise.
O so pe awon osise ijoba kan ni won pe
oun gege bi awako lati gbe won loo sibi ti won ti fe e mu awon odaran kan, nibi
ti won ti mu Segun ati Kayode, ti won si gbe won lo si tesan olopaa.
Gbogbo oro ti Seun so kale wi pe ko si
nkan toun ko le fi bura ni Segun ati Kayode n so pe awijare ti ko lese nile
lasan lo n so nitori pe kii se emeeji otooto lawon ti jo sise yi papo, tawon si
gba owo gidi nibe.
Ni bayii, igbakeji oga agba olopaa Zone
2 to wa nilu Abeokuta, Ogbeni Adamu Ibrahim so pe dandan ni kawon foju won bale
ejo leyin tawon ba pari ise iwadii won, nitori pe won ko sese maa sise buruku
naa, ati pe iru won si po kaakiri be e.
No comments:
Post a Comment