Ope o, elewon metala gbominira l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 8, 2017

Ope o, elewon metala gbominira l'Ogun

Idunnu lo subu lu ayo awon elewon metala ti won so pe won si n reti lati gba idajo won lodo adajo, sugbon ti Adajo agba nipinle Ogun, Onidajo (Arabinrin) Adetokunbo Bukola Olopade so pe ki won maa lo ni ayo alaafia.

Ase ojiji yi la gbo pe o waye latari bi Adajo agba patapata lorileeede yi se ti pase wi pe ki awon olori adajo lawon ipinle kaakiri orileede yi loo sabewo sawon ogba ewon to wa nibe, ki won si fi ninu won sile lati le din awon eeyan to wa lawon ogba ewon naa ku.

AWIKONKO gbo pe lesekese ti ase yi ti jade lati enu Adajo agba patapata naa, iyen Attorney General of the Federation ni Onidajo Olopade ti gbera lo sogba ewon to wa niluu Ilaro, to si pase pe kawon metala ninu awon elewon ti won ko tii gba idajo won maa lo sile won pelu alaafia.

Ohun ta a gbo ni pe awon ti won gbominira yi ni ejo ti won n je ko to n kan to le mu ki won loo sewon.


Nigba to n soro, Olopade je ko di mimo pe "Igbese idagbasoke tuntun yi waye lati din awon elewon ku kaakiri orileede Naijiria, gege bi ase ti a tun ri gba lati odo adajo agba lorileeede yii wi pe ki awa olori adajo kaakiri ipinle loo sabewo sawon ogba ewon, ki a si fawon ti ko ye ki won wa lewon sile."

O tesiwaju pe "Paapaa awon ti won ti wa lenu ejo won lati odun 2012 si odun 2014, atawon min in ti won ti gbagbe won patapata sewon."


Olori adajo naa tun menuba wi pe eleekeji re e ti iru nkan bee maa waye lodun yii.

Bee lo rawo ebe sawon adajo kaakiri wi pe ki won gbiyanju lati je ki ejo ti won ba gbe wa siwaju won maa pe ki won to muu wa sopin, ki won si ri daju pe won n lo awon ileewosan tijoba lese lati le mu ki ipinu lati di awon elewon ku wa simuse.


Bakan naa lo rawo ebe sawon elewon to gbominira wi pe ki won rii daju pe won n lo anfaani ominira ti won ri gba lati fi gbogun ti iwa ibaje ati iwa odaran to tun le mu ki won pada sibe.

AWIKONKO gbo pe eto lati da awon elewon min in sile si n tesiwaju lawon ogba ewon to ku bii Oba ati Ibara to wa niluu Abeokuta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI