Okan awon olopaa ko bale mo rara nigba ti won gbo pe awon
ajinigbe kan tun ti ji omo orileese China ti won poruko e ni Lee Xian Qiang gbe
lagbegbe Ogere, ipinle Ogun lojo Monde to koja yi, toro naa si doro eni to gbe
odo min in.
Lee ti won ji gbe |
AWIKONKO gbo pe ipinle Kogi ni Lee ti m bo, to n si n lo silu
Abeokuta, ko too di pe awon ajinigbe naa pade e lona ni nnkan bii ago marun
irole, ti won si jii gbe lero wi pe yoo dowo fawon lai mo pe omi maa pada teyin
wogbin won lenu.
Ko pe ti won ji Lee gbe la gbo pe iroyin ti kan si Komisana
olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu, to si pase pe kawon olopaa SARS gba ise naa
se, ki won si ri awon odaran naa mu.
Ohun ta a gbo ni pe ko ju wakati meje lo tasiri awon
ajinigbe naa fi tu ninu akolo won ti won n sapamo sii, nibe ni won ti bawon
olopaa SARS naa woya ija, ko too di pe awon marun salo, towo si te okan ninu
won.
Eni towo te naa la gbo pe o ti bere sii ka boroboro fawon
olopaa bayii, to si ti seleri pe oun yoo mu won lo kaakiri ibi ti won ti le ri
awon to salo naa mu.
Agbenuso fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi to gbe oro naa s’AWIKONKO
leti so pe awon mefa lawon ti won ji Lee gbe, sugbon tawon marun salo pelu ota
ibon lara, ti ori si tako okan ninu won, eni tawon ti n foro wa lenu wo bayii.
Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti wa rawo ebe sawon araalu
pe ki won tete je kawon olopaa mo bi won ba sakiyesi awon to ni apa ota ibon
lara, nitori awon tawon n wa ni.
No comments:
Post a Comment