Ololufe meji to n lu jibiti ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 9, 2017

Ololufe meji to n lu jibiti ti ha o

Bunmi Adegbola, Eko

Pakopako lawon ololufe meji kan ti won n sise gbajue, sugbon towo olopaa ipinle Kano te lai pe yi n wo ni tesan olopaa, ti won si bere sii ka boroboro bi eye ayekooto.

Jessy ati Jenifer
Jessy to je omo bibi Ilu Mubi nipinle Adamawa ati ololufe e, Jennifer toun je omo ipinle Bauchi la gbo pe ise ki won lu awon eeyan ni jibiti ni won fi n jeun.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni se lawon ololufe meji naa maa n lo sodo awon to n taja, lati se bi eni to fe e ra oja, sugbon to je pe jibiti won fe e lu.

Ogbon ti won ni won maa n lo ni pe, tu won ba ra oja tan, to ba ku ki won san owo, won a so fun awon oloja naa wi pe awon yoo san owo naa lati ori foonu awon, lati ile ifowopamo won, sugbon to je pe iro lasan ni.

A gbo pe ti won ba ti gba nomba eni ti won ra oja lowo e, won a wa fi atejise ranse sori e bi eni pe atejise ile ifowopamo ni, sugbon to je pe ogbon alumokoroyi ni.

Nigba tasiri awon mejeeji yi maa tu, obinrin kan la gbo pe won loo ba ra oja, ti won si fee dogbon se bi won tun se maa n se, sugbon tiyen tete ka won, to si pariwo won sita fawon eeyan ko too di pe won fa won le awon olopaa lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI