Ogundele gba ileese PDP l'Ogun, o lawon maa gba ijoba lowo APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 6, 2017

Ogundele gba ileese PDP l'Ogun, o lawon maa gba ijoba lowo APC

Alaga tuntun ti won sese yan fegbe oselu PDP nipinle Ogun, Onarebu Sikirulai Ogundele ti so pe gbogbo nkan to ba gba lawon maa fun un lati gba ijoba lowo Gomina Ibikunle Amosun ti egbe oselu APC, nitori ona to n gba se ijoba ko boju mu to.

O soro yi lakoko to n bawon oniroyin soro ni olu ileese egbe PDP to wa niluu Abeokuta lakoko ti won loo gba ileese naa lowo awon to wa lowo e tele.

Nigba to n soro, Onarebu Sikirulai Ogundele so pe kii se pe awon deede wa a gba ileese egbe won, bi ko se pe pelu ase tawon ri gba lati ilu Abuja wi pe awon gbodo se abojuto gbogbo nnkan to ba je ti egbe naa daadaa, eyi ti ileese egbe naa je pataki.

Nje e ti ka a: http://www.awikonko.com.ng/2017/11/lo-ba-tan-sikirulai-ogundele-ti-gba.html

Ninu oro e, o so pe “A ti wa a gba Olu ileese wa ati awon nnkan to je fegbe oselu wa, PDP pelu ase ti a ri gba lati ilu Abuja wi pe a gbodo sabojuto gbogbo ohun ini egbe paapaa ileese egbe. A si ti wa a gba nirowo ati irose.

"Ti e ba ranti daadaa, mo ti figba kan so pe a maa gba ileese naa nigba ti asiko ba ti to, ti ko si nii si nkan to maa di wa lowo, tawon agbofinro naa yoo si sise won bo ti to ati bo ti ye.

Abewo Makarfi siluu Abeokuta ko lese nile - Bayo Dayo: http://www.awikonko.com.ng/2017/11/abewo-makarfi-siluu-abeokuta-ko-lese.html

"Awa oloye ninu egbe oselu PDP atawon oloye egbe naa tele lawon ijoba ibile kaakiri atawon atawon eeyan ja-nkan-ja-nkan to je omo omo egbe la ti wa lati gba ileese wa, ki a le gbe egbe wa tesiwaju.

"Gbogbo awon nkan ti ko boju mu ti won ti fi pamo sibi lati ti ko kuro, ti a si ti le awon janduku danu.

"Ko si nkan to fe e da wa duro, ko si wahala, ko da, a tun wa pelu orin ati ijo. A ti pinu lati dari egbe yi lona to boju mu, ki a si gba ife ati alaafia laaye. A si tun maa no owo ife ati ibasepo to dan monran sawon to n binu tele. A maa pe won, a si jo maa sise papo.

Gbenga Daniel ko nibi to n lo - Bayo Dayo: http://www.awikonko.com.ng/2017/11/gbenga-daniel-ko-nibi-to-n-lo-ninu-egbe.html

"A ni lati gba ipinle Ogun kuro lowo ijoba ti egbe oselu APC n se, nitori pe se ni won n se owo ilu kumokumo, ti ilana ti won fi n na owo ko boju mu to.

" A ti lo kaakiri lati ye gbogbo awon nkan to wa ninu ogba yi ye wo, a si ti rii pe opolopo nkan ni won ti bake, ti won tun ti ko lo, ti owo won si le ni milionu marun un naira.

Ko seni to le di mi lowo lati dupo alaga PDP - OGD: http://www.awikonko.com.ng/2017/10/ko-seni-to-le-di-mi-lowo-lati-dupo.html

"A maa gbe igbese to ba ye labe ofin, a si tun maa duro lati gba ase lowo awon olori wa lati mo igbese to ye ka tun gbe labe ofin. A ti seleri fawon omo ipinle Ogun wi pe a maa yi oju ti won fi n wo wa pada si daadaa, a o gbodo dari egbe yi pelu jagidijagan."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI