Aare
teleri lorileede yi, Oloye Olusegun Obasanjo ti so gbawon oloselu orileede yi
lamoran wi pe ki won se jeje nitori pe eto oselu ko ye ko je nkan to n la iku
lo.
Obasanjo
soro yi lai pe yi niluu Calabar nipinle Cross River nibi ayeye ifilole iwe
tuntun kan ti won pe akole e ni "Stepping Forward with Uti J.D.
Agba", eyi ti Goddy Jeddy Agba ati Mathias Okoi - Uyouyo ko.
Oloye
Obasanjo to tun je Balogun Owu niluu Abeokuta, eni to je alejo pataki ojo naa
je ko di mimo pe oloselu to ba ni ijakule lakoko eto idibo gbodo gba kamu ni,
ko si tun fowosowopo pelu eni to ba jaws olubori lati le je ki alaafia wonu ilu
wa.
Ninu
oro e, o so pe "Oro oselu ko ye ko je emi ati iku. Eni ti ko ba olori awon
iranse, ko le je igbakeji olori awon iranse, nitori pe olori awon iranse ko le
da ise naa se. O gbodo fowosowopo pelu awon min in."
No comments:
Post a Comment