Nitori iyawo ti mo fee fe ni mo se loo jale - Okoro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 10, 2017

Nitori iyawo ti mo fee fe ni mo se loo jale - Okoro

Benson Akintunde, Ondo

Oro buruku toun terin ninu ogba oluleese olopaa Ondo lojo Tosde ana to koja yii nigba ti okunrin kan, eni odun merinlelogbon (34), Chukwuma Olori bere sii ka boroboro wi pe nitori iyawo toun fe e fe sile loun se loo yan ise ole jija laayo.

Okoro
Okoro to so pe Efo (Vegetables) loun n ta nigba to n b'AWIKONKO soro so pe obinrin kan loun fe e fe sile, toun si ti loo mo awon ebi e, sugbon ti won so pe koun loo mu owo to to egberun lona oodunrun (300,000) naira wa gege bi owo ori (dowry) toun ba mo pe looto loun nife omo won.

O lawon toun soro naa fun lo bere sii fi oun se eleya wi pe koun loo wa ibi kan jokoo si nitori pe eru toun fe e gbe ti ju toun lo, sugbon ife aisetan toun ni si omobinrin naa lo fa toun fi pinu pe nnkan to ba gba loun maa fun un.

Okoro tesiwaju pe latigba ti won ti soro naa foun loun ti n ronu ona toun fe e gbe e gba lati ri owo to po to bee yen, koun si loo ko fun awon molebi iyawo toun fe e yan laayo.

Itiju naa lo je koun pinu lati loo jale, toun si ti n wa ona lati ri ibi toun yoo ti jale naa, sugbon nigba toun maa ri ona abayo, eni kan lo ta oun lolobo nipa omobinrin kan to n sise nibi ti won ti n ta oti to fe e  gbe owo lo sile ifowopamo.

Ninu oro e, o so pe "Mo fee san owo ori iyawo afesona mi, sugbon mi o ni owo tawon ebi e beere lowo mi pe ki n lo mu wa, iyen egberun lona oodunrun naira.

"Iyawo afesona mi, atawon ebi e ni won sun mi si ole jija, nitori pe mi o jale ri, akoko ti mo ma a jale re e. Iyawo afesona mi lo ko eru e kuro nile mi lati nkan bi ose meta seyin, to si n be mi pe oun fe e pada.

" Mo nife e dokan, mi o si fe ki won fi fun okunrin miran, idi ni yi ti mo fi pinu lati wa owo naa ni gbogbo ona. Ko si bi mo se le ri owo to po bee yen, idi ni yen ti mo fi loo jale. Awon ore mi n fi mi se yeye nitori pe iyawo mi sa kuro nile lo sodo awon ebi e.

O ni lesekese toun ti gbo loun ti gba tele lati gba owo naa lowo e, iyen owo to to egberun lona eedegbeta (500,000) naira.

Bee lo so pe ibi toun ti fe e gba owo naa lo ti n ba oun se agidi, toun si gbiyanju lati yinbon fun, sugbon ti ibon naa ko yin, ko too di pe ariwo e jade sawon araadugbo naa leti, ti won si wa a raga bo oun mole.

Ninu oro e, o ni "Awon kan lo ta mi lolobo wi pe omobinrin kan n gbe owo lo si banki, mo wa ranse pe olokada kan, mo si ti so iye ti mo maa fun, to si gba lati ba mi sise naa.

"A ti loo duro de nibi to maa gba, gbogbo bi mo se gbiyanju lati ja baagi to ko owo naa si lo ja si pabo nitori agidi to ba wa se. O tun ti okada wa subu, ti a si subu sile. Mo wa a fa ibon kekere kan yo lapo lati yin in fun un, sugbon iyalenunlo je pe ota ibon ko jade.

"Lesekese ni olokada yen ti sa lo, to fi emi nikan sile, mi o le tete dide nile ko too di pe awon eeyan to wa ladugbo naa de lati wa a raga bo mi mole."

AWIKONKO gbo pe bi kii ba a se opelope wi pe awon alaanu tete ta awon olopaa lolobo ni, tawon naa si tete gbera lati lo sibe, die lo ku ki won dana sun in nitori ta a gbo pe won ti so taya sii lorun, ki won fina sii lo ku, ko too di pe awon olopaa de be lati gba a sile.

Ogbeni Femi Joseph to je agbenuso fawon olopaa ipinle Ondo nigba to n soro lakoko naa so pe dandan ni ko foju bale ejo tasiko ba ti to, iyen leyin tawon ba tubo se iwadii e daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI