Nitori ipo aare: Ajo omoleyin Kristi lawon ko fowo soya lori Fayose - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 3, 2017

Nitori ipo aare: Ajo omoleyin Kristi lawon ko fowo soya lori Fayose

Bolorunduro Ajayi, Ekiti

Ajo omoleyin Kristeni lorileeede yii,  Christian Association of Nigeria (CAN) ti so pe awon ko fowo soya lori ipinu Gomina Ayodele Fayose tipinle Ekiti lati dupo aare orileede yi lodun 2019.

CAN lo soro yi lati fi tako iroyin kan ti won lo m lo kaakiri ori ero ayelujara wi pe awon ti bu owo lu Gomina Fayose lati di Aare orileede Naijiria lodun 2019, ati pe iroyin ti ko lese nile lasan ni, nitori naa, kawon eeyan ma ka oro naa si.

Ninu atejade ti Bisoobu Stephen Adegbite to je oludari ajo naa lapapo fowo sii lojo Tosde to koja yi, lo ti so pe awon ko leti lati bu owo lu ipinu oloselu lati du eyikeyi ipo, sugbon tawon kan le gbadura si Olorun lati yan adari gidi fun Naijiria.

Ninu atejade naa ti eda e te AWIKONKO lowo, o so pe "A ri iroyin kan gba wi pe iroyin kan n lo lori ero ayelujara wi pe ileese wa ko iwe kan jade lati fi bu owo lu ipinu Gomina Peter Ayodele Fayose tipinle Ogun Ekiti lati di Aare lodun 2019. Iro to jinna si ooto oro ni, kawon eeyan kaakiri agbaye ma si se gba iroyin naa gege bii otito.

"CAN, gege bi a ti mo, o je agboorun fun awon elesin kristeni lorileeede Naijiria; nitori naa, bawo ni yoo ti wa seese lorile aye yii lati jade sita gbangba lati bu owo lu adije sipo kan?

"Nnkan ti a n se gege bi ara kan naa ni ka gbadura si Olorun lati yan awon adari ti yoo se ife Olorun, ti yoo si mu itunnu bawon eeyan e nipase isejoba to dara. A kii bu owo lu adije, a ko tii se rii, a ko si fe e bere e bayii.

" A n gba gbogbo awon omo leyin Kristi lamoran lati tesiwaju nipa gbigbadura fun orileede yii, Naijiria, ati adari sawon nnkan to n lo lonii lati se aseyori nipa jije kawon eeyan je mudunmudun oselu ijoba awaarawa lai fi toro eleyameya tabi esin se."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI