Nitori egberun mejo aabo: Tansogu pa omodun mejila fun oogun owo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 22, 2017

Nitori egberun mejo aabo: Tansogu pa omodun mejila fun oogun owo

Pakopako ni Tansogu Yewhenu, eni odun marundinlogoji n wo nigba towo awon osise Fijilante, iyen Vigilante Group of Nigeria (VGN) te e lojo Aiku Sande to koja lo lohun, leyin toun ati ore e, Soji Asamo ji odomobinrin eni odun metadinlogun (17), ti won si tun seku pa a lati fi soogun owo.

Adugbo kan ti won pe ni Idosemo nijoba ibile Ipokia, ipinle Ogun la gbo pe won ti ji odomobinrin naa ti won pe oruko e ni Taye Kosanu gbe lakoko to n kiri pofu-poofu ti egbon e, Oke Femi Maria to n gbe lodo e gbe le e lori lojo Tosde to koja lo.

AWIKONKO gbo pe nigba ti asiko to ye ki Taye pada sile latibi to ti kiri lo, ti won ko rii ni won ba a lo foro naa to awon olopaa leti, sugbon nigba ti won ko tete rii ni won tun loo fi to awon Fijilante to wa nitosi won leti, iyen lojo Satide to lo lohun.

Lesekese lawon naa ti bere sii se iwadi lati mo ibi ti omo naa wa, ko too di pe won ri Yewhenu ati Soji ti won tun n pe ni Apase nibi ti won ti n sise buruku kan ti won si fura si won ni nkan bi aabo mejila koja iseju die, loru ojo Aiku Sande to lo lohun, ti won si mu won.

Ohun ta a gbo ni pe bi won se rowo to awon mejeeji yi ni Soji Asamo ri aaye na papa bora, sugbon ti asiri e tun pada tu sawon VGN min in lowo ni nkan bii aabo meta oru ojo naa, ti won mu oun lo si tesan olopaa lesekese.

Nigba ti won maa tu baagi ti won ba lowo Yewhenu, iyalenu lo je pe awon nkan bii eya ara eniyan ni won ba ninu e, ti won si foro wa a lenu wo, to si jewo pe oun ati ore oun to salo lawon joo ji omodebinrin naa gbe.

Yewhenu so pe nigba tawon ji Taye gbe, ile akoku kan to wa lagbegbe Igude lawon tan an lo wi pe awon fe ba a ra pofupoofu, nibe lawon ti yanju e.

O lawon ge ori e, oyan e mejeeji, apa e mejeeji, nkan omobinrin abe e, die ninu ifun e ati okan e lawon yo, tawon si ju oku e sinu konga ile naa.

Nigba to n fidi isele naa mule fun AWIKONKO, Ogbeni Olanrewaju Adedoyin Nureni to je oludari Fijilante, VGN nipinle Ogun so pe nigba ti iroyin naa te oun lowo, loun ti pase fun awon osise abe oun to wa lagbegbe naa pe won gbodo wa omo naa ri.

Adedoyin so pe o seni laanu wi pe awon odaran naa ti yanju omodebinrin tawon obi e gbe pofupoofu le lori pe ko kiri lo, ti won si tun ge eya ara e lo, bee ni won tun so o sinu konga.

O so pe ninu oro ti odaran naa so lo ti so pe okunrin kan, to poruko e ni Soji Asamo lo ran awon nise buruku pelu adehun egberun mewaa naira, sugbon to san egberun mejo aabo naira fawon wi pe tawon ba pari ise naa tan lawon yoo to o gba owo to ku.

Nigba to n gba enu Komisana olopaa Ahmed Iliyasu soro lati fidi e mule, Abimbola Oyeyemi to je agbenuso so pe looto ni ati pe ise iwadii si n lo lowo.

Oyeyemi nigba to n gboriyin fun awon VGN naa so pe iwadii si n lo lowo, tawon si maa gbe won lo sile ejo pelu awon to ran won nise naa lai pe yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI