Bunmi Adegbola, Eko
Minisita foro iroyin ati asa lorileeede yi, Ogbeni Lai Muhammed ti so pe oun ko tii pa iro kankan ri latigba ti won ti bi oun sile aye, bo tile je pe oruko oun fee je mo iro (liar), sugbon ko nii se pelu iwa omoluabi toun ni.
Minisita foro iroyin ati asa lorileeede yi, Ogbeni Lai Muhammed ti so pe oun ko tii pa iro kankan ri latigba ti won ti bi oun sile aye, bo tile je pe oruko oun fee je mo iro (liar), sugbon ko nii se pelu iwa omoluabi toun ni.
Lai Mohammed |
Lai Muhammed soro yi niluu Eko lojo Tosde to koja lakoko to n bawon oniroyin soro, to si tun so awon ipenija to n koju lati odo awon to pe legbe alatako, iyen PDP.
Ninu oro e lo ti so pe "Ipenija nla meji ni mo ni. Akoko ni wi pe emi nikan lawon egbe alatako n wo, tawon egbe oselu PDP ko si tii forijin mi, ti mi o si lero wi pe won le dari ji mi.
"Oju nkan to sele si won ni won fi n wo mi, won si ro pe emi gan an ni igi leyin ogba fun nkan naa, leyi ti ko ye ko ri be, ti ko si boju mu.
"Sugbon, mo se iwon ti mo le se. Niisinyi ti mo tun je oju oju fun ijoba, ko si ani-ani wi pe gbogbo nkan to ba ti n wa lati odo Lai Mohammed, awon gbodo kaa si wi pe obitibiti iro lo wa nibe.
"O seni laanu wi pe, Baba mi lo so mi ni Lai. O je nkan to rorun fun won lati ka mi si oniro. Sugbon nkan temi naa ma fi n pe won nija wi pe ki won wa a so nkan kan soso ni pa to, ti mo so to je iro. Mi o tii pa iro kankan rii.
"E le ma gba mi gbo, sugbon nipa okodoro ati onka, mi o tii so nkan ti to le je ki won ma gba mi gbo. E ko nilo lati gba oro mi gbo, sugbon e ko le paro wi pe okodoro oro ni mo ma n so"
No comments:
Post a Comment