Oruko
ko ro odomokunrin eni odun merinlelogun (24), Lucky Ehioboh ti won lo n foruko
gbajugbaja onisowo ile Afrika nni, Ogbeni Mike Adenuga lu jibiti ko ro o mo
nigba towo olopaa ipinle Ogun te e lose to koja, to si bere sii bebe pe ki won
se oun jeje nitori pe ise esu ni.
Lucky |
Gege
b'AWIKONKO se gbo, won ni ori ero ayelujara abanidore kan ti a mo si Facebook
ni Lucky ti won ni omo bibi ipinle Edo ni ti n lu awon eeyan ni jibiti owo, ati
pe oruko gbajugbaja onisowo Mike Adenuga lo fi n lu awon eeyan ni gbajue naa.
Nigba
tasiri odomokunrin Lucky yi maa tu, okunrin kan ti won poruko e ni Abiodun
Olalekan Ogunseye lo lu ni jibiti owo to fi die le ni milionu kan (1,028,770)
naira.
A
gbo pe se ni Lucky pelu oruko ati Foto Adenuga lo fi paro fun Olalekan wi pe
oun yoo ba a wa ise si eka ileese epo robi, iyen Nigeria National Petroleum
Company (NNPC), ti o ba ti le san milionu kan aabo naira, sugbon ti okunrin naa
ko ro o lemeeji pe bo ya won fe e gba oun ni.
Lesekese
ni Abiodun ti so pe oun yoo san ninu owo naa, ati pe ti ise naa ba ti bo si
tan, loun yoo to o san eyi to ku, ki o le tete je ki ise naa ya, nitori ta a
gbo pe Lucky ti so fun un pe awon alase ileese NNPC naa loun fe e fowo di lenu
ki won le gba a si ise.
AWIKONKO
gbo pe bi Abiodun Olalekan se san owo naa tan, loju e sese to o la wi pe won ti
fi Eko han oun lori ero ayelujara, to si fibinu loo foro naa to awon olopaa
leti.
Ko
pe ti won fi so pe awon olopaa rowo to Lucky nibi to n gbe, nitori ti won so pe
ojo Aje Monde, iyen ojo kefa osu yii lowo te.
Iyalenu
lo tun je pe nigba ti won maa loo ka Lucky naa mole, foomu olowo nla (iPhone)
mefa, ero ayarabiasa komputa kan, sim card mejo ati kaadi ATM orisi banki marun
un ni won ba ninu ile e to fi n lu awon eeyan ni jibiti ki asiri e ma ba a tete
tu sita.
Ni
bayii, ohun ta a gbo ni pe, Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti seleri wi pe
ileese won yoo foju Lucky ba ile ejo leyin tawon ba tubo paro ise iwadi won
nitori wi pe aimoye awon eeyan lo seese ko ti pa lekun.
No comments:
Post a Comment