Looto ni mo n pawoda - Darasimi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 1, 2017

Looto ni mo n pawoda - Darasimi

Epe rabande lawon to gbo nipa ayederu pasito ijo Kerubi ati Serafu kan to wa n'Ijoko Ota, Darasimi Rotimi tawon olopaa ipinle Ogun foju e han fawon oniroyin lose to koja n gbe okunrin naa se.

Darasimi ati Sunday
Ohun ta a gbo ni pe Darasimi, Sunday Ibikunle ati okunrin kan ti won n pe ni Ogo Eri, sugbon toun ti na papa bora leyin tasiri won tu sita la gbo pe won gbimo pa odomobinrin kan Sara Olowokere, ti won si yo gbogbo eya ara e lo.

AWIKONKO gbo pe orebinrin Ogo Eri ni Sara to won demi legbodo naa, Sunday lo si fo igi mon on lori titi temi e fi jabo, ti won tun he ori, owo, oyan to fi mo okan ati nkan omobinrin e ni won fa lo.

Bo tile je pe se ni Darasimi n so pe oun ko mo nkankan nipa eni ti won pa, sibe Sunday n tenumo on wipe bi won ba fiya je e daadaa, o maa jewo fun won nitori pe kii se akoko e niyen.

Sunday, eni ogoji odun to nise okada loun n se so pe oun loun fo igi mo Sara lori to fi ku, toun si ge ori e lo, ati pe Darasimi ati Ogo Eri ni won yo eya ara e toku, ti won si tun lo sinku e sadugbo Alafia, Alagbole.

Darasimi so pe looto nise owo oun ko mo nitori toun maa n pawoda, sibe oun ko mo nkankan nipa esun ti won fi kan oun, ati pe bi won ba gbe obe soun lorun, ko tun mo si pe koun jewo nkan toun ko mo nipa e.

Nigba to n fidi isele naa mule, Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu so pe odaran ponbele lawon eeyan naa, nitori ti won da emi omolomo legbodo, ti won tun yo awon eya ara e lo lati fi setutu.

AWIKONKO gbo pe ogba SARS lawon eeyan naa si wa nibi ti won ti n foro wa won lenu wo, paapaa lati ri Ogo Eri to salo mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI