Lo ba tan; Sikirulai Ogundele ti gba ileese PDP l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 6, 2017

Lo ba tan; Sikirulai Ogundele ti gba ileese PDP l'Ogun

Idunnu lo subu lu awon omo egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP nipinle Ogun lojo Aje Monde onii, nigba ti Onarebu Sikirulai Ogundele atawon oloye egbe tuntun ti won sese dibo yan ninu egbe oselu naa se loo pada gba ileese egbe won (Party Secretariat) to wa ni adojuko NNPC niluu Abeokuta.

Ogundele
AWIKONKO gbo pe ojo Abameta Satide to koja yi ni won dibo yan Ogundele gege bi alaga tuntun fegbe oselu PDP nipinle Ogun bo tile je pe orisirisi awuyewuye lo ti wa nile tele wi pe boya idibo naa ko nii waye, sugbon ti won pada se e nirowo-irose.

Gbongan ayeye ti Olusegun Obasanjo, iyen OOPL ni won ti se eto idibo naa, nibi ti awon agbaagba egbe oselu naa lapapo, to fi mo alaga won patapata lorileeede yii, Ahmed Makarfi ti wa nibe.

Awon oloye egbe tuntun
Leyin idibo naa ni Onarebu Ogundele ti gba gbogbo omo egbe lamoran wi pe ki won fi ife ba ara won se po, ki won si je ki wahala to wa nile di ohun I gbagbe.

Bee lo seleri wi pe oun yoo ri daju pe oun yanju gbogbo konun-n-koho to ba wa ninu egbe oselu naa, toun yoo si tun pe gbogbo awon to ba ye jokoo lati jo so asoyepo.

Bakan naa lo rawo ebe sawon omo egbe naa pe ki won fowosowopo pelu awon nitori pe agbajowo la fi n soya, toun yoo si maa fi bo ba se n lo to won leti.

Lakoko ti won n dunnu
Lara awon ti won tun yan ni Wole Ojosipe, Alaaji Ismail Odejinmi, Kayode Adebayo, Wale Adeogun ati Irede Oginni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI