Leyin wahala odun meta Faithia loun ti yo Balogun kuro ninu oruko oun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 3, 2017

Leyin wahala odun meta Faithia loun ti yo Balogun kuro ninu oruko oun

Bolorunduro Ajayi, Ekiti

Ko si iroyin meji lagbo osere tawon Yoruba to n lo kaakiri igboro bayii, bi ko se ti eni tawon eeyan mo si Fathia Balogun tele, sugbon to so pe Faithia Williams loun fe e maa je pada bayii.

Gege b'AWIKONKO se gbo, bo tile je pe o le lodun mewaa ti Saidi Balogun ati Faithia ti jo ko ara won sile, sugbon lati nnkan bii odun meta seyin ni Saidi ti n pariwo pe oun ko fe ki iyawo oun tele naa si maa lo oruko (Balogun) oun.

Faithia to ti bimo meji fun Saidi la gbo pe o ti figba kan so pe ko si nkan to buru toun ba n lo oruko baba awon oun, nitori pe oko oun si ni, bo te je pe awon ti ko ara won s, sugbon nitori toun ti bimo fun un.

Be o ba gbagbe, AWIKONKO muu iroyin awon mejeeji wa fun un yin lai pe yi lori bawon mejeeji tun se pada soro si ara won latigba ti won ti ja ajatuka. Ilu Abeokuta lawon mejeeji ti pade, ti won si di mo ara won, debi wi pe won fe e fenu ko ara won lenu.

Oserebinrin kan to n je Toyosi Adesanya lo sokunfa bawon ololufe meji tele yi se ba ara won soro fun bii iseju meji, to si ya gbogbo awon eeyan lenu nibi ayeye aadota odun ti Ogbeni Kayode Akindina tawon eeyan mo si Emir ati Mr Paragon se ni gbongan ayeye DLK to wa niluu Abeokuta.

Ni bayii, ohun ta a gbo nipe gbogbo awon foto ti Faithia ti ya sori eka ero ayelujara ti won pe ni Instagram lo ti yo kuro, to si tun ti paaro oruko e kuro ni faithiabalogun si faithiawilliams bayii.

Bee la gbo pe o ti n pinu lati kuro lori ero ayelujara nitori itiju to seese ko ri gba lati odo awon eeyan to n tele lori ero ayelujara naa.

Fawon to ba mo Faithia daadaa, won yoo mo pe Williams to fe e pada maa je bayii ni oruko baba to bii lomo to n je tele ko to o pade Saidi, ki won to o fe ara won.

Ohun kan ti a tun ri gbo bayii ni pe, ipase okan lara awon oserebinrin egbe e, Toyin Aimakhu, toun naa yi oruko pada si Toyin Abraham loun naa fe e to bayii, ti yoo si je kawon eeyan mo pe Faithia Williams loun n je bayii.

E ma je ko ya yin lenu wi pe ko too to odun to n bo, oruko tuntun naa yoo ti rinle kaakiri agbaye nitori awon imura to ti n mu lori e.

Bakan naa la gbo pe gbogbo igbese lati paaro oruko yi lo ti n gbe labele tipetipe, ti ko je ko han sita, to si ti se atunse lori awon ibi to ti se akosile oruko naa, bii affidavit abbl, ko to o di pe o gbe e sita faraye lati mo nipa e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI