Oba Olugbenle |
Olu
Ilaro soro yi lakoko to n gba awon igbimo ileese ibanisoro, MTN to n sagbateru
ayeye odun Oronna lalejo ni Aafin Asade Agunloye to wa niluu Ilaro lai pe yi
fun ipalemo ayeye naa.
Kabiyesi
so pe latigba ti ayeye naa ti bere ni ife, alaafia ati isokan ti wo ilu Ilaro,
eyi to mu ki ilu naa maa tesiwaju laarin awon ilu to ku kaakiri orileede yi.
Nigba
to n gbawon omo Yewa lamoran, Oba Olugbenle so pe awon eeyan ko gbodo je ki asa
ati ise ile naa parun latari esin ti won tewo gba lati odo awon oyinbo alawo
funfun.
O
so pe ile Yoruba nikan lo ni asa ati ise to se e fowo soya le lori nitori
tinwon n fi iwa omoluabi se, ti won si n bowo fun asa pupo kaakiri awon eya to
ku lorileede Naijiria.
Ninu
oro ti e, alaga igbimo eto ayeye naa, Alaaji Rafiu Akinola so pe ona ara oto ni
ayeye odun fe e gba sele latari awon eto olokan o jokan ti won ti la kale fun
un, lati muu larinrin.
Akinola
so pe eto naa ti yato si ti tele, ti ona ti won n gba se too si yato patapata,
ati pe awon olorin lorisirisi ni won ti fiwe pe lati wa a dawon eeyan laraya,
lara won ni Reminisce, Small Doctor, Chris Daniel atawon olorin min in ti
gbogbo won je omo bibi Yewa.
O
wa gbawon oloselu, paapaa awon to ti n gbero lati di ipo gomina nipinle Ogun
lamoran wi pe ki won ma se lo anfaani ayeye naa lati fi se ipolongo idibo.
No comments:
Post a Comment