Nise lawon ti won n ba odomokunrin kan ti won pe oruko e ni Dele Adele la enu
won sile lojo Wesde ose to koja yii nigba tawon tu inu yara e, ti won si ba
orisi ibon ilewo meji nibe pelu ota ibon la enu won sile ti won ko le pa a de
nitori to je iyalenu fun won.
Dele Adele |
Gege
bi iroyin to te AWIKONKO lowo, won so pe isesi Dele ti won ni odun
mejidinlogbon (28) ni to mu ifura dani ladugbo to n gbe, lo je kawon kan lo
foro naa to awon olopaa leti.
Eyi
la gbo pe o fa tawon olopaa agbegbe Oke-Itoku nitosi Sapon fi gbera lati loo
sewadi Dele ti won so pe okada lo fi n sise, ti won tun loo ye inu ile e wo.
Lara
awon to gbe oro naa si wa leti so pe kani Dele mo pe awon eeyan kan n fura soun
ni, o seese ko ti ko awon ibon tawon olopaa ri ninu yara e kuro, ko si ti loo
toju e sibi tenikeni ko ti bii fura.
AWIKONKO
gbo pe seni Dele koko paro wi pe oun ko nkan nipa esun tawon eeyan fi kan oun,
sugbon nigba ti won bere sii tu inu yara e, ni won ba awon ibon naa ninu iho to
wa labe kapeeti e.
Lesekese
lo ti dobale wi pe ki won se oun jeje, nitori pe ogbologbo adigunjale loun,
sugbon toun n fi ise okada naa boju nitori pe ise okada kii se nkan teeyan le
si gbogbo ara de.
Ni
bayii, Ohun taa gbo ni pe tesan awon olopaa ni Dele si wa nibi ti won tun ti m
foro wa a lenu wo, lati le jewoo awon akegbe e to ku, ki owo si le te won.
No comments:
Post a Comment