Ijoba ipinle Ogun lawon setan lati satileyin fegbe FIBAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 8, 2017

Ijoba ipinle Ogun lawon setan lati satileyin fegbe FIBAN

Ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun lawon ti se tan lati satileyin fegbe sorosoro, iyen Freelance and Independent Broadcasters' Association of Nigeria (FIBAN) nipinle naa.

Femi Omilani
Komisana foro idagbasoke agbegbe ati egbe alajeseku (Community Development and Cooperatives), Onarebu Gbenga Adenmosun loro yi lakoko tawon oloye egbe naa, to fi mo alaga won, Komureedi Olufemi Omilani sabewo si ofiisi e to wa ni Oke-Mosan niluu Abeokuta.

Nigba to n soro, Adenmosun so pe ijoba ipinle yoo sa gbogbo ipa ati agbara e lati rii daju pe egbe naa tubo fese mule daadaa sii, ati pe ajosepo to muna doko yoo tubo bere bayii.

O wa dupe lowo alaga egbe naa, Komureedi Omilani fun ise takuntakun to n se nipa ilosiwaju ati idagbasoke egbe sorosoro naa latigba to ti di alaga.


Saaju akoko yi ni Omilani ti je ko di mimo wi pe ko si nkan meji to fa abewo naa bi ko se pe lati fi egbe naa han sijoba ipinle Ogun, ati lati yi erongba ijoba nipa egbe naa pada si daadaa.

Lakoko abewo naa
O ni awon awuyewuye kan lo n lo labele wi pe egbe won ko satileyin fun ijoba ipinle Ogun, eyi to je pe iro to jinna si otito oro patapata ati pe egbe won kii se egbe oloselu leti ti ko le fun awon lanfaani lati tele enikan, bi ko se kawon sagbateru ijoba to ba wa lori aleefa.

Omilani wa lo akoko naa lati fi dupe lowo ijoba ipinle Ogun paapaa Komisana Adenmosun gege bo se gba won lalejo, to si fi ife bawon soro.


Lara awon to tele alaga egbe naa, Omilani lo sibi abewo naa ni Olumide Awolowo; Ayobami Adelani; Adebisi Oseni to je akapo egbe; Kehinde Ibrahim topo mo si Van Garuba; Daud Alapotiowo; Wale Elegbede atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI