Oga agba ajo Fijilante, iyen Vigilante
Group of Nigeria nipinle Ogun, Ogbeni Adedoyin Olanrewaju Nureni ti so idi Pataki
ti Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ko fi maa n ri aaye lati sun. Adedoyin
so pe ko si idi Pataki ti Gomina Amosun ko fi maa n ri aaye lati sun, bi ko se
nipa oro eto aabo emi ati dukia awon araalu. O soro yi lai pe yi lakoko to n b’AWIKONKO
soro niluu Abeokuta. Idi ni yii, to fi so pea won ti n pinu lati fi Gomina
Amosun ni ami eye idalola gege bii Gomina to mu oro eto aabo lokunkundun laarin
awon Gomina to ku lorileede Naijiria. E ka bi iforowero naa se lo.
OLANREWAJU: Oruko mi ni
Olanrewaju Adedoyin Nureni, emi ni oga agba, iyen komanda ajo Fijilante ijoba
apapo nipinle Ogun, iyen Vigilante Group of Nigeria (VGN).
AWIKONKO: E je ka mo die nipa
yin, bi e se bere atawon ileewe ti e lo.
OLANREWAJU: Agboole Labuta ni Owu Abeokuta
ni mo ti jade. Ojo kerindinlogun osu kefa lodun 1972 ni won bi mi. Mo bere
ileewe alakobere ni Abeokuta North Primary School, ni Ita-Olori, ibe ni won ti
ko wa lo sibomin in ti won so oruko ileewe naa ni Abeokuta South Local
Government School. Mo tesiwaju lo si ileewe girama Macjob nibi ti mo ti se tan
lodun 1990. Mo lo si ileewe akosemose, iyen Technical College to wa ni Ayetoro,
odun 1994 ni mo se tan ni be. Mo tun lo sileewe kan nipa eto isoro, ti a n pe
ni Accounting Technician Scheme, Institute of Chartered Accountant (ICAN), nibe
ni mo ti gba oye Associate Accounting Technician (AAT) lodun 1998. Mo tun wo o
pe eko ko gbodo duro sibe, mo tun lo gba foomu HND ni ileewe giga gbogbonise
Moshood Abiola, ti mo tun ko eko nipa isiro owo, Accounting. Nitori awuyewuye
tawon eeyan n so pe imo eko BSC ju ti HND lo je ki n tun lo gba foomu ni
Yunifasiti Crescent to wa niluu Abeokuta, ti mo si gba oye Bachelor of Science
(BSc, Hons). Mo tun te siwaju lati loo ko eko nipa eto aabo, ti mo si gba oye
PGD ni eka ikekoo Criminology and Security Studies ni Yunifasiti NOU, iyen
National Open University. Mo tun se Masters mi naa leka ikekoo Peace and
Conflicts Resolution. Lowolowo bayii, mo tun ti n kekoo nipa ICAN mi pada ni
Professional Level, igba die lo ku ki n se tan nibe. Ko tan sibe, mo tun ti gba
foomu PhD ni Yunifasiti Ibadan leka ikekoo Peace Conflicts and Resolution.
AWIKONKO: Ise Fijilante, ki lo fa
a to fi je pe oun le yan laayo, bawo le se bere?.
OLANREWAJU: Mo maa n so fawon eeyan wi pe ise
Fijilante ti wa latigba ti Olorun ti da Adamu sori ile aye wi pe ko maa so ogba
ati ayika ti Olorun da, to si fi si ikawo e, idi ni yii ti a fi n pe ni egbe
ojulalakanfinsori ni yen. Bo tile je pe a ti n se ni ifinufido ni agbegbe wa
kaakiri, sugbon odun 1999 la da a sile lodo ijoba, lati le mo nipa e. Odun 1990
lawon to n se kaakiri orileede yi bere sii ko ara won jo, ti a si wa a pada
forikori lodun 1999 lati fi oruko naa lele lodo ajo to n mojuto idasile ileese
lorileede Naijiria labe akoso oga wa, Usman Mohammed Jahun.
E je ki n
menuba bi mo se yan ise naa laayo, nigba ti mo n se HND mi lo ni MAPOLY, ise
karakata ni mi n se, mo maa n ta moto, mo si maa n gbe fawon eeyan ni
san-die-die. Mi o ronu lo sibe nigba naa, sugbon nigba to di odun 2008, mo n wo
telifisan lodun naa lohun ni, mo wa a ri oga agba wa patapata, iyen Alaaji
Jahun tawon osise telifisan AIT n foro wa won lenu wo. Imura won lo wu mi lori
pupo pelu awon oro ti won so nigba naa, bo tile je pe a ti n sise Fijilante naa
ladugbo wa diedie, sugbon mi o mo pe won ti n wo yunifoomu, idi ni yii ti mo fi
loo darapo mo won lati jo gbe ise naa laruge. Igba ti mo wo inu e daadaa ni mo
wa a pinu lati loo ko eko nipa eto aabo to pe ye lati le ni enu oro nipa eto
aabo lojo iwaju. Eyi lo fun mi ni anfaani lati mo nkan ti a n pe ni eto aabo,
ati bi a se le soro nipa eto aabo.
Lakoko idanilekoo |
AWIKONKO: Bawo wa a ni Fijilante
ipinle Ogun, VSO se wole ti e fi darapo, nitori pe inu egbe VSO lawon eeyan mo
pe e wa tele?
OLANREWAJU: Ibeere to dara le beere yen. VGN
ni gbogbo wa wa tele, iyen pelu awon to wa ninu egbe VSO lonii. Oloogbe Femi
Bisiriyu lo je adari wa nipinle Ogun nigba naa, ti a n se pelu ifinufido. Nigba
ti Gomina wa oloriire, Ibikunle Amosun n se ipolongo idibo nigba ti won ma a
koko wole, won ran awon eeyan wa ba oga wa Bisiriyu, nigba ti won ri ise ti a n
se. Won ni ka se agbateru won, won si seleri fun wa wi pe awon yoo se daadaa si
wa, ti won si mu ipinu won se. Nigba Ibikunle Amosun wole gege bii gomina lodun
2011, won ranse pe wa ni gbongan Obas Complex to wa ni Oke-Mosan, won si
inaugurate wa pelu oruko Vigilante Group of Nigeria lodun naa lohun. Gbogbo
moto atawon nkan ti won ko fun wa nigba naa, oruko VGN lo wa nibe. Igba to ya
la gbo ti won so fun wa wi pe oga olopaa ipinle Ogun nigba naa so pe ka oruko
min in ti a ma maa je, ki a yi oruko VGN pada, ibe ni oruko Vigilante Service
of Ogun State, VSO ti jeyo. Bo tile je pe VSO la n je nipinle Ogun, sibe VGN la
n je ti a ba loo se ojuse wa niluu Abuja. Sugbon ni bayii, onikaluku ti da
duro, won ni ka rin ka po, yiye ni n ye ni. Ko si nkan to buru ti ipinle Ogun
ba ni Fijilante ti e, ti ijoba apapo naa si ni ti e. Oju orun to eye fo lai fi
apa kan ara won, ati pe aisi ise gan an maa tun dinku lorileede Naijiria wa
ni.
Okan lara awon iwe |
AWIKONKO: O ti pe odun kan gbako
bayii ti e di oga agba ajo VGN nipinle Ogun, ki ni e le so gege bi awon aseyori
yin?
OLANREWAJU: Looto ni, o ti pe odun kan
bayii, orisirisi ise lati se, orisirisi nkan naa la ti se. A ti lo kaakiri
ipinle Ogun lati polongo fun won pe iwa odaran ko da, ati bi won se le ran awon
eleto aabo lowo nipa iwa odaran lagbegbe won. Elo min in hu iwa odaran ti ko
mo. Eni ti omobinrin sa lo ba nile, to de omo naa mole, to kii mole to n ba a
sun, towo agbofinro ba te, esun ajinigbe ni won maa fi kan an nile ejo. Ko si n
kan to n je pe mi o mo nile ejo. Awon omo kekeeke kan wa to je pe won toro owo
kaakiri, ti won si n tibe ko egbekegbe, gbogbo eyi la n je kawon eeyan mo pe
ohun gbogbo lo wa labe ofin. Ko lo n ka odaran la ti mu, ti a si ti fa won le
awon agbofinro lowo. Nigba kan la gbonpe awon omo Bado fe e yoju nipinle Ogun,
lesekese lati so fawon osise wa kaakiri ijoba ibile lati ba won se ipade wi pe
a o gbodo gbo pe Iru e sele nipinle ti a wa. Bo tile je pe o fe e sele, sugbon
ti Olorun tete ba wa segun won nipa bi a se da awon osise wa sita. A tun ti se
ojulowo kaadi idanimo to je pe ilu oyinbo la ti loo gbe ero ero ti a fi se e
wa, eyi ti ko ni fun awon to n se ayederu lanfaani lati se ayederu e jade. A
tun ti gbe iwe aba lo sile igbimo asofin niluu Abuja lati so Fijilante di ofin
lorileede Naijiria. Laarin odun kan si asiko yii, ile igbimo asofin kekere
niluu Abuja ti by owo lu, o ku ki ile igbimo asofin agba, iyen Senate by owo
luu, ti a si nigbagbo pe lai pe, won a bu owo luu, ko too di pe Aare wa, Ogagun
Muhammadu Buhari naa towo bo, ti VGN yoo si di tijoba apapo. A tun ti lo
kaakiri igberiko atawon agbegbe lati bawon eeyan soro lori ona ti won le eto
aabo to pe ye gba ni adugbo won. A ti bere eto lori redio ati telifisan lati le
je kawon eeyan maa mo bo se n lo nipa eto aabo.
AWIKONKO: Ki ni ajosepo yin pelu
ijoba ipinle Ogun atawon ajo eleto aabo to ku nipinle Ogun, bii olopaa,
sifudifensi atawon min in?
OLANREWAJU: Ajosepo to dan monran lo wa
laarin awa ati ijoba ipinle Ogun, ti a ba ni nkan lati se, a maa n ko iwe si
won, tawon naa si n ko iwe si wa. Bakan naa ni awon ileese eleto aabo to ku naa
la jo n sise papo, ti owo si n wonu owo. Ni bayii, eto kan n lo lowo ti a n
gbaradi fun lati se, a fee fi aami eye da Gomina wa, Ibikunle Amosun lola, ti e
ba wo awon ipinle kaakiri orileede yi, e e rii pe Gomina Amosun nikan lo fe e
je gomina to mu eto aabo lokunkundun, nitori pe ko si nkan to n lo ti won ko
mo. Ki n kan too sele, won ti gbo, won si ti wa ona abayo sii. A fi bi eni pe Gomina
wa kii sun ni, to ba ti kan eto aabo, idi ni yii, ti a fi woo pe o ye ka fi ami
eye, awoodu da Gomina wa lola, gege bi Gomina to dara ju nipa oro eleto aabo de
lorileede Naijiria.
AWIKONKO: Ise eto aabo
ojulalakanfinsori, iyen Fijilante, awon eeyan gba pe ko see foju lasan se lai
te nidii. Ona wo leyin n gbe ti yin gba. Ati pe nje e nigbagbo ninu oogun
abenugongo?
OLANREWAJU: Olorun ni kan la wa nigbagbo
ninu e, nitori pe oun nikan lo ba lori ohun gbogbo. Eni to ba ti fi Olorun se
agbekele e, o di dandan ko se aseyori. Nipa ti oro oloogun de, emi o nigbagbo
ninu e, nitori nkan ti mo mo ni pe Olorun lo ju ohun gbogbo lo. Ti a ba wa
gbogbo awon odaran ti owo awon agbofinro atawon eleto aabo ti ba latigba ti a
yi da orileede yi sile, opo ninu won naa ni a n gbo pe won ni oogun lowo. Mi o
tii ri eni ti won mu, ti oogun e maa so pe ki won ma muu. Dandan ni ki won mu,
ki wa la wa n ba kaakiri? Ki ni itunmo oogun ti won wa ni, to sunko. A o tun fi
be e gbojule le ibon naa tan, nitori pe owo la fi n mu awon odaran, paapaa awon
ole, ati pe a ko tii gba ase lati maa a lo ibon. Idanilekoo ti a n se fawon
osise wa lo maa n je kawon eeyan ro pe oogun la n lo, aye ti a wa ninu e yi ti
laju ju oogun tawon baba wa gbojule late atijo lo.
Kaadi Idanimo |
OLANREWAJU: Ese gan an fun ibeere yi. Mo fe
e fi gbogbo enu so fun un yin pe kii se omo egbe Fijilante ijoba apapo, iyen VGN
ni nkan ti e so yii sele sii. Ti a ba wo o, orisirisi eeyan lo n pe ara e ni
Fijilante. Awon baba kan wa ti won wa ladugbo, ti won n so adugbo, Fijilante
lawon naa maa pe ara won ti won ba fe e soro, idi ni yii ti a fi n wo aso
idanimo, iyen Yunifoomu lati le je kawon araalu da wa mo yato si awon to ku.
Kii se omo egbe wa, o le je awon ti won kii wo yunifoomu, tabi awon ode adugbo.
Mo so fun un yin leekan wi pe awa ko tii ma a lo ibon, a ko tii gba ase lati
maa lo ibon. Awon kan wa to je pe won n fi ibon won pa eran igbe ninu igbo,
awon min in naa si le ni iwe ase, tawon min in o si ni. Teeyan ba si ni ibon to
ni iwe ase ninu ile, tawon ole ba wa ka a mo, dandan ni ko koju ibon si won,
iru awon be e, ti won wa laarin wa ni mo mo pe won ni ibon.
AWIKONKO: Bawo le se n se
Idanilekoo fawon osise yin?
OLANREWAJU: O kere ju, eekan losu la maa n se
Idanilekoo fun won. O le lati oro awon alase wa lapapo, tabi lati odo awon
ijoba ipinle, igba min, o le je awon to wa nijoba ibile lo maa sagbekale e lati
ko ara won jo, lati mo nibo lo tun ku sii. A maa n ranse pe awon olopaa, awon
otelemuye atawon ileese eleto aabo min in. Idanilekoo kan ta a se niluu Abuja
lai pe yi, awon ileese eleto aabo kan ni won wa lati ile Iroopu (Europe). Won
wa a da wa lekoo lori nkan ti a n pe ni odaran (terrorism). Nigba ti a se tan,
mo wa lara awon meji ti won yan lati tele won lo siluu won lati loo wo bi
ileese won se ri, atawon nkan ti a tun le jo se papo. A ti lo sawon orileede
bii Russia, Germany, United Arab Emirates (UAE), Dubai atawon min in bee bee
lati rii pe a n kogbon lara awon orileede min in. A si ti n lo gbogbo ogbon ti
a lo n ko lodo won, ti a si ri pe o n sise fun wa.
AWIKONKO: Kin ni in afojusun yin
lojo iwaju nipa eto aabo orileede Naijiria?
OLANREWAJU: Pelu igbese ti ijoba apapo n gbe
lowolowo ba yii nipa eto aabo, paapaa ajo Fijilante, mo nigbagbo wi pe wi pe
odun mewaa si asiko ta a wa yii, atagba eto aabo (security network) lorileede
yii a je eyi to dara ju, leyi to je pe eeyan kan ko kan le daran, ko si se be e
salo. Eeyan kan ko le wa lati ilu kan loo daran niluu miran, ko si salo.
OLANREWAJU: Amonran mi a koko lo sodo ijoba
apapo, pe ki won tete ba wa jara mo iwe we to ti wa nile igbimo asofin agba
niluu Abuja bayii, ki Aare Buhari le tete ba wa bu owo luu, nitori mo nigbagbo
wi pe awon gan an ni won maa bu owo luu, ki ise eto aabo wa lorileede yii le
tubo gbooro sii. Amonran mi sawon araalu ni pe ki won rii daju pe won n tubo fowo
sowopo pelu osise eyikeyi to ba wa lagbegbe won, ki a si ma je ki irewesi okan
mu wa. Bakan naa fawon osise wa, maa gba won niyanju wi pe ki won tu bo ni
suuru, nitori pe ibi ti won ti n ba a bo jinna, a si ti fe e de ibi ti a n lo.
Ki won si rii pe won n fi ife bawon araalu sise.
No comments:
Post a Comment