Gomina
ipinle Ogun, Asofin agba Ibikunle Amosun ti ro awon olokoowo kekeeke, ati
olokoowo nla wi pe ki won wa da ise sile nipinle Ogun pelu bi won ti se ka
ipinle naa mo awon ipinle marun un to lowo ju lo lorileede Naijiria.
Gomina
Amosun soro yi nibi ipate oja ita gbangba (Lagos International Trade Fair)
eleekokanlelogbon (31st) iru e to sese pari niluu Eko nigba ti igbakeji e,
Arabinrin Yetunde Onanuga n gba enu e soro.
Amosun
so pe pelu awon eto ti ijoba ipinle naa ti se lati le je ki eto oro aje ipinle
naa lo soke lo je kawon olokoowo to to eedegbeta (450) wa nipinle naa lasiko
yi.
O
lawon yoo ti daju pe awon eto to tun si n lo lati je ki ipinle Ogun wa lara
awon ipinle ti yoo maa figagbaga pelu awon orileede kaakiri agbaye lawon yoo je
ko wa si imuse.
Nigba
toun naa n soro, Komisana foro ileese ati okoowo, Ogbeni Bimbo Asiru je ko di
mimo lati je ki ipinle Ogun fa awon olokoowo mora lo fa ti won fi pinu lati je
ki awon opopona kaakiri ipinle naa fun wo lo ju, ti won si tun se e rin, ti ko
si ni fa idakureku moto.
Bee
lo so pe aaye si sile gbayau fawon to ba fe e wa da ise sile nitori tawon ti
lese orisirisi nkan alumoni amayederun to le mu ki ise tabi oja lo bo se ye ko
lo lasiko.
Bakan
naa lo tun fi kun oro e pe bi ibi teeyan ba ti n sise ba se rorun to, ti
alaafia si wa lo le je ki ifokanbale wa fawon onisowo.
No comments:
Post a Comment