Onimo Ero Adebayo Adedayo ti so pe Otunba Gbenga Daniel to je oludije sipo alaga gbogboogbo fegbe oselu Peoples Democratic Party, PDP ko nibi kankan to n lo, nitori pe ni se lo n tan ara e je lasan ni. Adedayo so pe bi Gbenga Daniel ba gbe apoti kanselo ni woodu e ni Sagamu, ko le wole nitori awon wahala to ti da sibe. Bakan naa lo tun so pe ijoba etan nijoba Muhammadu Buhari, paapaa isejoba egbe oselu APC lorileede Naijiria. Okunrin naa soro yi lojo Abameta Satide to koja lo lakoko to n b'AWIKONKO soro nile e to wa niluu Ijebu Igbo. E kaa bi iforowero naa se lo.
Bayo Dayo |
AWIKONKO: Oruko yin?
BAYO DAYO: Oruko mi ni Onimo
Ero Adebayo Adedayo, ti mo je alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun
AWIKONKO: A gbo pe
awon kan ninu egbe oselu yin tun n pinu lati dibo min in labele lonii ojo
Abameta Satide, ojo kerin osu kokanla (November 4, 2017), ki le ri si, ati pe igbese
wo le fe e gbe labe ofin?
BAYO DAYO: Gbogbo egbe to ba je
egbe nla bi egbe oselu PDP, a gbodo mo wi pe orisirisi awon eeyan lo maa wa
nibe. Bi awon to da a se po ninu egbe wa naa ni awon to ku die kaato naa wa.
Sugbon leyin ti a se ipade apapo to gbe wa wole la ti n gbo awuyewuye won, a si
lo sile ejo, ile ejo si so pe awa gan an la ni eto lati je agbateru egbe wa,
lati woodu titi de ijoba ibile ati ijoba ipinle. Nigba ti kootu ti soro yi
jade, ti ko si tii si ile ejo to gbe idajo naa ti segbe kan, ko si nkan
tenimeni tun le se, bi ko se pe ki awa naa si maa tesiwaju gege bii ojulowo
agbateru egbe naa. Gbogbo awon to sa lo sodo Makarfi ni won so pe oun lo ye ko
wa nibe, a si ba won gba a be pe oun ni oga gbogbo wa, lati din wahala ku,
sugbon ibi yi won n ba oro lo yii, won fe e ba egbe je ni. Ti Makarfi ba je eni
to mo bi won se n to egbe, o ye ko pe otun ati osi lati beere ona ti a fe e gbe
e gba lati pana wahala to n sele, sugbon Makarfi gan an funra e ko figba kan
gbe apoti, iran lo wa a wo ni Port Harcourt tawon Ayodele Fayose si rii nibe,
ti won pe e pe ko wa maa se olori egbe lo. Sugbon gbogbo agbateru e to n se lo
maa dopin lojo kesan an osu kejila ti a ba lo sibi ipade gbogboogbo nitori pe
osu merin pere ni won fun in tele ki won to o sun siwaju di osu to m bo, iyen
Disemba. A si ba a gbadura pe ki Olorun ka ise rere mon on lowo.
AWIKONKO: Abewo
Makarfi siluu Abeokuta, ki le ro pe o le je abajade abewo to fe wa a se na?
BAYO DAYO: Emi o rii gbo pe
Makarfi n bo niluu Abeokuta nitori pe gege bi ilana se so, ti olori ba n lo
sibi kan, o gbodo fi to awon ara agbegbe naa leti lati maa mura sile. Sugbon
eni to m bo lati ilu Abuja wa silu Abeokuta, o gbodo so fun alaga ipinle naa pe
oun n bo lakoko bayii, won a si se eto ayeye bi won se maa pade e, sugbon eyi
ti Makarfi n se ko ye enikan nitori pe o ti wa si odo Baba wa Olusegun Obasanjo
ti a si se ayeye bi a se maa pade e, ti gbogbo awon omo egbe si ti loo duro
sile ise wa, ti a ko si rii. Eyi ti won tun so pe o n bo yii, mi o mo nkankan
nipa e, sugbon a ba awon to n bo wa ki ku oriire.
AWIKONKO: Pelu bi Otunba
Gbenga Daniel se n lo kaakiri wi pe oun fe e di alaga egbe lapapo, nje e ro pe
o le jawe olubori pelu wahala to wa ninu egbe oselu PDP nipinle Ogun to ti fe e
jade?
BAYO DAYO: To ba je pe lotito
ni Otunba Gbenga Daniel fe e se alaga egbe oselu nla bii ti PDP lorileeede
Naijiria, o gbodo koko tun ile se naa, ko too so pe oun fe e bo si gbangba. Ti
Gbenga Daniel ba gbe apoti kanselo lowo to wa yii, ko le wole ni Sagamu nitori
gbogbo awon asemase to ti se seyin, ko too tun wa so pe oun fee lo se alaga
egbe lapapo, o n tan ara e je ni, nitori pe o n lo sile ejo lojo Monde to n bo
yi l'Abeokuta lori esun ole jija ti ajo EFCC fi kan an. Eni ti ko tii yanju ara
e nile ati nile ejo, to je pe oun gan an leni to n da ile ru nitori pe oun ni
olori wa nipinle Ogun nigba to m se gomina. O ku die ko pari saa isejoba e lo
so pe oun ri nnkan to bi oun ninu, to si lo da egbe oselu min in sile, iyen
PPN. Igba to tun rii pe egbe naa ko larinrin to bo se fe, o tun lo darapo mo
egbe oselu Labour. Osu kewaa odun 2014 lo tun pada wa sinu egbe oselu PDP. Ni
bayii, o sese pe odun meta ninu egbe oselu PDP ni. Ojo to ti kuro ninu egbe lo
ti padanu ipo agba e. O sese tun bere sii to ara e pada gege bi omo egbe tuntun
ni. Emi gangan ni mo loo gba waiver fun nitori eni ti ko ba tii pe odun meji
ninu egbe ko le gbe apoti, emi ni mo ko rekomendason (recommendation) leta lo
siluu Abuja nitori oun ati Adebutu lati le gbe apoti. Apoti naa ni won gbe, to
so Adebutu di Onarebu, apoti naa ni Dani fee gbe, to gba foonu seneto, sugbon
ti ko seese fun un, to je pe Buruji Kasamu lo gba ipo naa mo lowo. Ipo ti
Kasamu gba mo Daniel lowo titi di onii lo m bi Daniel ninu. Gbenga Daniel ko
nibi to n lo, ere lasan lo n se. Oun funra e mo pe oun ko le wole. Egbe oselu
PDP nipinle Ogun ko fowo si Gbenga Daniel lati di alaga lapapo. A ni awon to je
pe won ni oruko, ti won ni ipo, ti won si tun ti se daadaa seyin ninu
egbe. A o si le firu awon to loruko, ti won ko si tun ni abawon sile, ka wa so
pe iru eeyan bii Gbenga Daniel la fe loo mu.
AWIKONKO: Ninu gbogbo
awon to jade lati dupo alaga egbe oselu PDP lapapo, ta ni e lero wi pe o le se
e ti enu awon omo egbe yoo fi ko?
BAYO DAYO: Iyen soro lati
dahun, nitori pe bi enikan ba so pe oun mo igbeyin oro, aje ni won maa pe iru
eni bee. Mi o mo igbeyin nkan to le sele lohun, sugbon mo mo pe Olorun nikan lo
le so eni to maa jawe olubori. Lara awon ti enu si n kun labele wi pe won le se
e; eni akoko ni Ojogbon Adeniran, eni ti gbogbo wa gba wi pe oun ni olori wa.
Nigba ti awon bii baba wa Bola Ige so pe awon ko se PDP mo, Adeniran leni naa to
gbogbo eeyan n lo sodo e niluu Ibadan. Ile e lawon agbaagba ti lo n se ipade ko
too di pe PDP fese mule ni gbogbo ile Yoruba. Nitori e la se mo pe Adeniran ye,
o si to lati se e.
AWIKONKO: Ni nnkan bi
osu meloo kan seyin ni egbe oselu PDP nile Yoruba so pe awon da Buruji Kasamu
duro nipinle Ogun, gege bi alaga, nje ase naa fese rinle bii?
BAYO DAYO: Mi o gbo nkan to jo
be nitori pe eni to ba maa da Seneto to si wa lori ipo duro, a fi ti won ba so
nile igbimo asofin egbe naa. Abuja ni won le ti so nkan to jo be, ti won ko si
so be. Looto ni won n so pe won maa fiya je e, sugbon won ko se nkan sii, oro
enu lasan ni. Eni kan soso to n na owo apoti e lati fi ko egbe naa jo, ko ma si
le parun, Buruji Kasamu leni naa. Bi Gbenga Daniel se maa gba gbogbo owo egbe
PDP, to maa ko sapo lo n wa, iru awon bii Gbenga Daniel ko le na owo egbe. Ti
won ba fe ki egbe PDP parun nipinle Ogun, ki won so fun Seneto Buruji Kasamu
kuro ninu egbe. Awon egbe to n fe ti Buruji Kasamu po repete wi pe ko kuro ninu
egbe PDP, to ba si fi le kuro, egbe naa maa ku patapata ni. Gbogbo owo ti a so
pe a n na ninu egbe PDP, ko seni meji to n lowo sile lo bi ko se Kasamu, lati
woodu, titi de ijoba ibile ati ijoba ipinle, oun nikan leni to gbe egbe yi duro
nipinle Ogun.
AWIKONKO: Ipade
gbogboogbo egbe PDP to n bo lai pe yi niluu Abuja, nje e setan lati yoju sibe?
BAYO DAYO: Awa ni ijoba, awa si
ni ojulowo omo egbe ti orin ijoba fowo sii, awa naa la si maa wa nibe. Gbogbo
awon omo egbe to ye ko lo lati ijoba ibile, woodu ati nipinle lo n lo patapata.
AWIKONKO: Gbogbo egbe
oselu ni won ti n gbaradi fun idibo odun 2019, bo tile je pe ko si egbe oselu
ti ko ni wahala ti won labele. Nje egbe PDP ti gbaradi fun eto idibo to n bo
naa?
BAYO DAYO: Egbe oselu PDP gan
an lo gbaradi pupo ju fun idibo 2019, lara igbaradi naa ni awon wahala te n ri
to n sele yii nitori pe onikaluku lo maa polongo ara e pe oun da a, sugbon egbe
PDP nikan soso ni a mo to wa lorileeede Naijiria niisinyi, ti enikeni le maa
soro e ti a ba n soro egbe, nitori awon eeyan ti won lawon maa senji gbogbo nkan
to wa Naijiria ti senji kuro nibi to da a si buruku. Awon eeyan si ti fee senji
pada sinu nnkan to da a bayii nitori ko seni to fe nkan buruku. Gbogbo nnkan to
n lo ni Naijiria bayii la ti rii pe kii se nkan to lo daadaa. Awon to wa nibi
ijoba niisinyi ni won ko mo bi won se n se ijoba. Won ni won n mu awon to n
kowo je, awon funra won, ogbologbo ninu owo ki ko je, gbogbo eeyan lo n so, ti
won n be PDP wi pe ki won pada. Won ni ka pada di okan soso. Nkan tawon eeyan
fe ni pe ka pada sipo. Lagbara Olorun, PDP lo maa pada gba ijoba lodun 2019.
AWIKONKO: Lai pe yi,
won ni ipinle wa lara awon ti IGR won lo soke, nje Amosun se daadaa lori eyi?
BAYO DAYO: Ona meji lo pin si,
ka kan maa ka nkan ninu iwe wi pe owo to n wole po jaburata, ko ma si wole, ko
je pe iro nla (propaganda) la fi n se, ona kan niyen. Ona keji ni pe ki owo
wole, sugbon ka ma naa sona kan. Bawo la se maa je awon tisa lowo, iyen owo ti
won n yo ni won ko le da pada. O ti pe osu mokanlelogun ti won ti n yo owo
tisa, ti Amosun ko le da pada. Gbogbo ise to ye kijoba ibile se ni won ko le
se, nitori pe awon gan an ni won nise to po ju lati se. Eni to so pe biriji
loun fe e fi gbogbo owo to n wole nipinle Ogun se, to tun wo ile onile. Ase
pati lo n tun n se opo ninu awon ise naa. Orisi meji ni Oba to wa; Oba to n so
egan di erufu, Oba to so erufu degan. Sugbon oba to n so egan derufu ni Amosun,
oba to n so ilu di igbe ni Amosun. Ijoba e ko tu awon eeyan lara, bee nijoba
Buhari ko tu awon omi Naijiria lara. Awon araalu naa si mo, ti won si n so pe
awon fe e ki PDP pada, ti a si maa pada.
AWIKONKO: Abiodun
Akinlade, omo egbe oselu yin, igba to ya, o salo sinu egbe oselu ACN, o tun ya
o tun pada si PDP, niisinyi, APC lo wa bayii, to si n leri pe oun yoo ko gbogbo
omo ile igbimo asofin lo sinu egbe APC naa. Ki le ri sii??
BAYO DAYO: Gbogbo naa la n gbo,
ko si egbe oselu kan ti Akinlade ko tii se ri. Ti igba ti won ba n ja di ipo
bayii ba n bo, ni Akinlade maa n lo lati ibi kan sibi kan. O ti so fun Ibikunle
Amosun wi pe oun maa ko gbogbo awon omo ile igbimo asofin lo sinu egbe APC. A si
mo pe ko le ri awon tegbe PDP ko lo, bo tile je pe o ti mu enikan lo sodo
Ibikunle Amosun pe ko se daadaa fun un, to si maa ko awon to ku pe won n bo
lodo e, sugbon ti a mo pe ko seni to n tele e lo sodo Amosun. Opolopo ninu awon
omo wa ni won n ro pe ti Amosun ba fun Akinlade ni tikeeti Gomina, awon maa
tele e, emi si mo pe Akinlade ko le ri tikeeti Gomina gba. E je ki Ibikunle
Amosun mu tikeeti Gomina le Akinlade lowo naa, igba yen la sese maa mo ibi to n
lo atibi ti ko nii lo, nitori gbogbo eeyan lo fe se ore Gomina. Ibi ti
oro si wa bayii ni pe ki won si fun ni tikeeti.
AWIKONKO: Ti a ba ni
ka woo, o fe e je pe egbe oselu yin nikan ni won maa n gbe ara won lo sile ejo
laarin awon egbe oselu to ku nipinle Ogun, igba wo gan an lo fe e dopin?
BAYO DAYO: Mo fe e fi da gbogbo
omo Naijiria loju wi pe ile ejo lo n gba gbogbo omo mekunu sile lowo awon
aninilara. Eni to ba si mo eto e labe ofin lo n lo sile ejo, nnkan to dara
niyen. Igba meloo le ti wa sileese wa, ti e ri wa ti a ko ada ati ibon? Ko si
gbogbo iyen, nitori pe nnkan ti ko je kiru nkan bee maa waye ni pe ile ejo lo n
ti wa leyin. Ibikibi ti won ba ti n gbe ibon ati ada, e ko le ri mi nibe,
sugbon to ba di oro ile ejo, bo je ile ejo mewaa ni leekan soso, mo setan lati
lo sibe, ju wi pe ki n lo maa yo ada ati ibon. Ko tii seni to si mo nkan to n
bo ninu egbe oselu APC, Olorun lo mo rogbodiyan to si n bo laarin won, sugbon
iru e ko le sele lodo ti wa, nitori pe ile ejo lo n pari oro wa. Ibi ti won ba
si so o sii, ibe lo maa duro sii. Eni to ba wa so pe ori oun gbe iso, wi pe oun
ko ni tele ase ile ejo, kiru eni bee lo maa roko oba sile ni, nitori ewon niru
eni bee maa gbeyin sii. Ile ejo te wa lorun ninu egbe PDP ju ka maa ko ada ati
ibon kaakiri lo. Ile ejo la nigbagbo ninu e, nitori pe ile ejo lo gbe Makarfi
de ipo to wa lonii. Ti Makarfi ko ba lo ile ejo (Supreme) to ga julo, ko le di
alaga egbe lai lai. Ki si ona abayo min in ju ile ejo naa nitori pe ile ejo lo
mo bi won se n to nkan.
AWIKONKO: E sapejuwe
isejoba Aare Muhammadu Buhari ati ijoba APC lati bii odun meji aabo seyin.
BAYO DAYO: Ijoba ti gbogbo
eeyan lero wi pe awon nigbekele ninu won, ti won si maa se daadaa ni, sugbon bi
ojo se n gun ori ojo, ti osu n gun ori osu, a ti rii wi pe ko si nkankan ninu
ijoba yii. Nigba ti olori ogun ba ti sina, ki lo ku tawon omo ogun tun fe e se?
Nigba ti ara oga won ko ya fun igba to pe, onikaluku won lo be sita, won si
bere sii se nkan to wu won, lara nnkan to wi won ti won n se lawon nkan ta n ri
bayii. Gbogbo won la n gbo pe o n kowo je. Enikan ti e gbe ise bilionu
marundinlogbon (25bilion) jade lai je pe ijoba mo si, ti enikeni ko si gbo si.
A si ti ri ijoba yi gege bi ijoba to le si wa lokan, eni to si wi won ni won n
fi sipo. Won mu omobinrin kan wi pe won fe e fi se igbakeji gomina ile
ifowopamo agba (Central Bank), kin ni iriri omobinrin yii ni eka eto owo
(Banking), sugbon won fe e lo lati le eni to wa nibe kuro, ki won si fi ropo e.
Awa Naijiria, a fi ki a ma sun asunpara nitori nkan to le se wa lese ni. Ti a
ba sun asunpara, Olorun nikan lo le so nnkan to ma a sele. Nkan tawon to sunmo
Buhari niluu Abuja n gbero lowo yii, ko le so eso rere fun gbogbo omo Naijiria
ni. Gbogbo awon to wa nipo giga, eya Hausa nikan ni won ko sibe. Won ti ni
ipinu ti won fe e se. Hausa lomobinrin ti won fee fi sile ifowopamo yii, Hausa
ti se ri, Yoruba ti se ri, Ibo naa ti se rii, sugbon ki lo de to je pe Hausa
nikan ninwon doju ko ile ifowopamo to je ti gbogbo Naijiria. Gbogbo wa la ni
eto sii, sugbon kii se pe ki e lo mu eni ti ko kaju e lati se e sibe, eyi lo ya
emi lenu o. Ipinu Buhari kii se ipinu to dara rara. Ipinu buruku ni fun gbogbo
omo Naijiria o. Eni to ba sun, ko ma tilekun nitori pe Olorun nikan ki mo nkan
to n bo, Olorun a si gba ki nkan rere wa si Naijiria.
AWIKONKO: Amoran yin
lapapo?
BAYO DAYO: Amoran min fun
gbogbo omo Naijiria, paapaa awon omo egbe oselu PDP patapata, ki won je ki a ni
asepo to dan monran nitori pe nkan to le je ka se aseyori niyen. Mo be gbogbo
omo egbe PDP kaakiri Naijiria pe ki won je ka se asepo pelu isokan. Gbogbo nkan
ti a n so yi naa, awon odo la n se fun un nitori OE awon ni won ni ojo ola,
meloo niru awa yi le se nibe?, ki a ba awon odo se e sile ko le da a ni. Mo be
gbogbo awon to n ka oro mi yi loruko Olorun, ki won je ki a se asepo to dan
monran ninu egbe PDP nipinle Ogun ati lorileeede yii, ki ojo ola awon odo wa le
dara. Olorun oga ogo a si gba fun wa.
No comments:
Post a Comment