Gani Adams gbawon Oba ile Yoruba lamoran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 22, 2017

Gani Adams gbawon Oba ile Yoruba lamoran

Aare Ona Kakanfo tuntun, Oloye Otunba Gani Adams ti gba pupo ninu awon Oba ile Yoruba lamoran wi pe ki won tubo loo se iwadii nipa itan orirun won, paapaa nipa ojulowo itan Yoruba, ki won si le mo ibi ti ile Yoruba ti se wa gangan, nitori pe opo itan ti won n so fawon onkowe lo jr pe iro lo po ninu, tawon onkowe naa si tun n gbe jade gege bi won se gbo o.

Aare Ona Kakanfo
Otunba Gani Adams soro yi l'Ojobo Tosde ose to koja lakoko to n bawon eeyan soro lori isokan ile Yoruba nibi ayeye ifilole ati ikojade iwe itan Yoruba tuntun, eyi ti Olootu iwe iroyin Alariya Oodua, Ogbeni Oyekunle Babarinde ko, to pe akole e ni "Yoruba Ni Tooto".

O so pe o seni laanu wi pe pupo ninu awon Oba ile Yoruba ni won ko mo ojulowo itan isedale ilu ti won ti bi won, tawon naa ko si se iwadii lati mo ojulowo itan orirun won ti won ti jade.

Gege bo se so ninu oro e, Gani Adams so pe "Awon Alariya Oodua ni ki n soro die lori isokan ile Yoruba, bo tile je pe eni to koko da wa lekoo ti so die ninu e, sugbon maa kan fi die kun ni. Ona imo iwe ni oludanilekoo naa fi soro, sugbon emi a so temi gege bi iriri.

"Pupo ninu awon Oba ile Yoruba wa lara awon to da aisokan sile lorileede Naijiria lojo tonii, eyi ti awon onkowe da sile ninu e lo po ju. Ti onkowe kan ba wa lati Oyo, o maa ko itan e lona ti yoo sojurere fun Oyo ju ilu Ife lo. Ti elomin in ba wa lati Ile Ife, o maa ko iwe e lona ti yoo fi sojurere fun Ile Ife ju Oyo lo. Awon to wa lati Oke-Ogun maa ko iwe yen lona ti yoo sojurere fun ilu ti emi ti wa.

"Mo wa n fi asiko yi so fun un yin pe oro ile Yoruba gege bi opolopo itan ti a ti ka nigba ti a wa nile iwe lo si n fun wa ni wahala titi di oni. Mo gbo nigba ti won so pe ogun lo le Oduduwa kuro n'Ile Ife, lo si Subar, nigba to de Subar lo wa de ile Yoruba. Gbogbo itan yi naa la ka nile iwe, to tun je pe a maa fi n se orin ko lakoko ere tabi nigba ti a ba fe e se idanwo.

"Sugbon nigba ti a wo ijangbara, ti a wa rin kaakiri ile Yoruba, a wa a rii pe opolopo awon itan yi lo je pe awon Oyinbo atawon Fulani lo gba awon onkowe lamoran wi pe ki won ko o lona ti won fi ko o yen, lati si awon eeyan lona, ati "lati ma se je ki ogo Yoruba tooto je ohun ti a n gbe ga" (undermine unique sign of Yoruba race).

Oyekunle Babarinde
"Ki Olorun ko fi orun me Oba Okunade Sijuade, ohun lo je ka mo pe itan yen kii se bo se ri ni won se ko o yen, iro to jinna si otito ni. Ile Ife ti a soro e yii, Ile Ife keta la wa yi. Ife akoko ni Ife Oori; Ife keji ni Ife Odaye; Ife keta ni Ile Ife. Oyo ti a n ri yi naa, Oyo keta la wa yii. Oyo kinni ni Oyo Basita, Oyo Ile, Oyo Katangua; Oyo keji ni Oyo Igboho; Oyo keta ti a wa a wa yi ni Oyo Daporo.

"Sugbon ti a ba ni ka wo o, onikaluku won iwa ilara (ego) ni won fi ko itan won. Elomin in esin to n se lo je ko nkan to wuu fun wa. Mo wa a be eyin onkowe lonii wi pe ki e pada wa lo o se iwadii ijinle lori itan ile Yoruba. Itan yi gan an wa lara awon itan tawon Oba di muu, ti onikaluku n pa itan to wuu ni ileto e.

"Mo wa nipinle Osun lopin ose to koja, nitori pe eni to ba je Aare Ona Kakanfo, oye ile gbogbo Yoruba lo je. To o ba je Aare Ona Kakanfo, ti o si fe e gba iyi, irin gbodo wa lese baba alajo e. O gbodo lo sodo gbogbo awon Oba Alade nile Yoruba lati loo ki won, pelu awon eeyan to se daadaa nile Yoruba lo gbodo lo o ki.

"Ninu irin ajo mi, nigba ti mo de Ilesa, oto ni itan ti a gbo; nigba ti a kuro nibe lo si Iwo, oto ni itan ti a gbo; nigba ti a de Ejigbo, oto ni itan ti a gbo, to tun je pe awon oniroyin to tele mi, nigba ti won gbo orisirisi itan, se ni won n so pe 'oga o'. Gbogbo Aafin pelu itan otooto.

"Mo wa a fe e be eyin Ojogbon to je pe e maa ri aaye daadaa, nitori pe ise wa fun un yin lati se. Nigba ti won ba fi mi je oye naa tan ni ojo ketala osu kinni in odun to m bo, iyen January 13th, 2018, ma a se ifilole ajo (foundation) kan, to je pe ma a ko awon Ojogbon jo, ma a wa fi owo (money) tii leyin, ki won le loo bere ojulowo itan Yoruba.

Lakoko ifilole iwe tuntun
"Ki lo fa a, ti enu wa ko fi ko, ti amulumala fi wo aarin wa nile Yoruba, won ni odo to ba gbagbe orisun e maa gbe ni. Yoruba ti gbagbe itan won, bi olaju se n wole, ti ilu n fe si, opolopo Yoruba ti gbagbe bi Olorun se da won. Olorun asepe (perfect) ni Olorun to da wa.

"Olorun ti ko se asise ni. Olorun mo idi to fi da awon iran Larubawa, to fi fun won ni Kurani (Quran), to fi fun won ni ede Arabic, to fi fun won ni ile ase ti a n pe ni Kahaba. Olorun mo idi to fi da awon Israeli, awon Sioni, to fi fun won ni Oke-Sioni, to fi fun won ni odo Jodaani (River Jordan), o tun fun won ni ede Eberu (Hebrew).

"Olorun mo idi to fi da wa, ti awon kan maa fi da irungbon si. E wo awon Aafa atawon Imaamu wa, Olorun mo idi to fi so pe kawon Larubawa maa mura, ki won maa wo aso jalamia. Olorun naa lo wa mo idi to fi da awa Yoruba wi pe ki a ma a de fila Gobi, tabi fila abetiaja; ka wo agbada tabi buba ati sokoto.

"Olorun wa mo idi to fi fun wa ni ede wi pe ede Yoruba ni ki a ma a so. Olorun mo idi to fi so pe ki a ni isedale. Olorun mo idi to fi fun wa lawon ohun alumoni (heritage), to wa lori oke, ninu omi, lori ile, ninu afefe.

"Sugbon nigba ti awon esin igbalode wole, ti esin to ni irawo lorigun mereerin agbaye de, awa Yoruba gba awon esin naa, to je ka so isedale wa nu. Lara ibi ti wahala ti bere niyen. Yoruba so pe nkan eni kii di meta ki inu bi ni. Nigba ti esin Musulumi ati Kirisiteeni wole, nise lo ye ka fi kun eyi ti a n se tele ni, ko le di meta.

Olufilole iwe naa ati olukotan
"Sugbon ti elomin in ba gba esin Musulumi gbo, nise lo maa bu enu ate lu Kirisiteeni ati esin ibile to je abalaye. Aisokan (disunity) yen ti wa a wa lati agboole si agboole; o ti wa a wa ni ilu si ilu; orileede si orileede, ko da  egbe oselu. Won a so fun un yin pe ti e ba fe e je Gomina, gomina je Kirisiteeni, ki igbakeji e si je Musulumi.

"Awon nkan yen ni ka wo daadaa, ti a ko ba wo daadaa, ko ma je pe iru nkan to sele loke Oya (Northerners) wole to wa wa.

"Mo ba Oba kan pade, mi o ni daruko e, nigba to bere sii soro, o bere sii gbe ogo fun awon Fulani; o bere sii gbe ogo fun awon Emir, o si bere sii bu enu ate lu awon Oba, to si je pe Ade wa lori oun naa.

"Gbogbo nkan ti Yoruba ti n se lati aye iwase, ti Yoruba si ti wa ju egberun mewaa odun ko to o di pe won bi Jesu. Won bere sii bu enu ate lu gbogbo nkan ti Yoruba ti n se. Mo tun gbo ninu oro Oba naa to so pe awon babanla wa ko gbon, wi pe awa la gbon ju won lo. Awon oro yi ta mi lara nigba ti mo maa jade ninu Aafin e, nitori pe o se mi ni kayeefi, ti mo si wa a rii dajudaju pe irin wa lese omo Yoruba.

"Imura wa ni won fi n da wa mo. Nigba ti mo koko dide lati maa polongo asa, awon Yoruba ni won koko dide lati koju ija si mi wi pe mo n polongo orisa. Mo wa a so fun won wi pe mi o polongo orisa, asa ni mo n polongo. Asa yato si orisa, orisa naa tun yato si oro esin.

"Odun mefa lo gba mi ko too di pe awon Yoruba gba mi, ti won si fun mi ni ami eye gege bi eni to n gbe asa ga. Ki la n pe ni orisa? Orisa ni won n pe ni eni ti ori sa da, to je akanda, to n se nkan ti eeyan lasan ko le se. Orisa ni nkan to n sise ninu afefe, ti a o ri.

"Olorun Olodumare ni Orisa akoko, iyen Orisa Oke. Awon nkan ti a ni l'Osun Osogbo ati kaakiri ni a n pe ni orisa ile. E so pe orisa ko da, Ede (crab) to n jade ninu omi orisa le n je; Eja to n jade ninu omi orisa, e o le fi sere; awon nkan ti won gbe koja lori omi orisa ni e n lo; goolu to n jade lori ile orisa ni e n ta, ti e fi n ri owo sapo. Eyin Yoruba, e je ka ronu.

Babarinde ati Oyekunle
"Eeyan ko le so pe oun ri baba kan, ko wa a so baba e nu ki Eleda baba yen ma ja, opolopo Yoruba ni won ti so baba won nu, won wa so baba oni baba di nkan gidi. E je ka mu esin wa lokunkundun. Musulumi ni mi, baba to bi mi, musulumi ni, iya to bi mi, esin Kirisiteeni lonn se.

"Ki n to jade nile, mo ti gbadura, emi naa ni Pepe ninu ile. Awon eeyan ro pe ti n ba ti debi kan, oro orisa ni mo maa n so. Mi o le tori pe mo gba esin kan, ki n wa fi owo osi juwe ile baba mi.

"O seni laanu wi pe ninu agboole awon Oba, won ti pin ara won sona meji nitori oro esin. A ni awon Oba elesin Musulumi, bee naa la ni awon Oba elesin Kirisiteeni, e o wa nii gbo Oba elesin abalaye (Traditional Religious Obas). Nibo ni Yoruba n lo?. Bee, Oba to jokoo sori ite la n pe ni Traditional Ruler.

"Ki la n pe ni Ka-bi-e-o-si, igbakeji orisa; ki ni idi ti a fi n dobale fun Oba? Won kii dobale fun eeyan lasan, eeyan to ba de Ade sori ni won n dobale fun. Idi ti a fi n dobale fun won ni pe awon ni asiwaju esin abalaye. Oba ni asoju Olodumare.

"Awon Oba wa ni ise lati se lati le je ki won pa enu won po. A n soro isokan, e je ka wo awon nkan to n fa aisokan nile Yoruba. Akoko ni ayederu itan; eekeji ni bi a se n sa fun asa ati ise pelu isedale wa. Opo Yoruba ni won n mura eya min in, ti won ko fe e mura ti won mo. E o le de ile Ahusa ki e ri won pe won de fila Yoruba, sugbon awa n de fila ti won.

"Nitori ifekufe aye la se gbagbe orisun wa. Ise wa lowo wa lati se. Bakan naa ti e ba pe awon oniroyin sibi kan, nkan ti won n wa ni oro egbe oselu tabi iroyin aburu (crime news) lo ma n siwaju awon iwe iroyin won. Awon nkan abalaye wa ti a n sa fun yen lo n fa wahala ti a n koju.

"Ko eda alaaye kan to le so pe oun fe e le gbogbo nkan ti Olorun ko sori ile wa, afi ti Olorun ba so pe oun fe e yi won pada lo ku. Ti a ba n bu enu ate lu awon nkan ti a ni, eyi to ye ko si eso rere ko bii so.

"Ile Yoruba lo n ta ounje fun orileede Naijiria tele, ti a ba n so nipa ise agbe, a mo ipa ati akitiyan ti ile Yoruba se. Lonii, gbogbo awon omo wa to ye ko sise agbegbe ni won ti omo-ita sigboro ilu. Ti a ba fe e jade, a gbodo ko owo won dani, nitori pe won ko ni je ka gbadun ni gbogbo ibi ti a ba de.

"Awon omo to ye ki won ni eegun lati sise ni won ko le sise mo. Awon omo to ye ki won kawe lo je pe okada ni won n gun, ise agbero ni won n se. Ile iwe giga la ti n ri egbe okunkun tele, sugbon ni bayii, gbogbo ibi ni egbe okunkun ti wa, to je pe tawon oloselu ba ti fe e dibo, won a gba won, lati ko ibon le won lowo.

"Ninu awon omo wa ninu egbe OPC ni won maa n ya lo tele, sugbon ti a ti ka owo won ro. A ti fi epe le awon omo wa lori wi pe nnkan bayii lo maa sele si eni to sise buruku fun oloselu. Igba ti won wa rii pe won ri awon eeyan lo mo ninu egbe OPC ni won se pada lo sodo awon omo egbe okunkun.

Iwe naa re e
"E e ri awon omo wa ti won a maa fa sokoto won sile ti won ba n rin, awon elewon atawon omo geto (Ghetto) ni won maa n mura be ni Amerika. Awon obi tun ti n ko omo si ara won debi wi pe oto ni soosi ti baba n lo, oto ni soosi ti iya n lo, oto ni soosi ti omo naa maa lo, won a ti yi ori e pada lati ile iwe giga.

"Aisokan yen ti n bere lati inu ile, to fi de adugbo, to fi de ipinle, to fi wa a yika orileede. E je kawon olori esin wa aisokan ninu emi nitori pe nkan teeyan ko ba ri gba ninu emi, eeyan ko le rii gba ninu ara, ara ko le se e, emi lo le se e.

"Iran wa je iran ologo, gbogbo iran ologo lo ma n ni isoro lorigun mereerin agbaye. O nikan tawon eya kan ti fe lu fe ti won fi da ija sile laarin Akinola ati Awolowo; bee ni won se to fi je pe Yoruba lo gbogun ti Abiola lodun 1993. Asiko yi lo wa buru ju to je pe ti Yoruba ba fa nkan soke, Yoruba egbe e naa le maa ri to maa fa lo sile. Ota ara wa ti a ni laarin ara wa ti wa a ju ti eya min in lo.

"Mo wa a dupe lowo eni to fun mi ni aaye lati soro laarin yin lonii. Ni agbara Olorun Olodumare lai pe lai jinna, enu Yoruba ma a ko. Isokan a wole."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI