Fijilante ko se e foju lasan wo mo - Ganzallo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 21, 2017

Fijilante ko se e foju lasan wo mo - Ganzallo

Oga agba fun ajo Fijilante ipinle Ogun, iyen Vigilante Service of Ogun State, VSO, Ogbeni Soji Ganzallo ti so pe awon osise won ko se e foju lasan wo mo lasiko yi latari ise aabo emi ati dukia awon araalu ti won n se.

Ganzallo soro yi lakoko to n soro nibi asekagba idanilekoo olojo marun un ti won se fawon osise ajo naa ninu ogba idanilekoo won to wa niluu Ilaro lose to koja yii.

O so pe kii se tuntun mo pe loore-koore lawon n se idanilekoo fawon osise won, sugbon eyi ti won se yi lo je asekagba e fun todun 2017 to n pari lo yii.

Oga agba naa so siwaju pe ise eto aabo ko ba ma ti dagba soke bo se wa lonii ti kii ba a se ifowosowopo ati bi ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun, ati bi oro eto aabo tun se je e logun.

AWIKONKO gbo pe ipele keji ti won pe Batch B ni idanilekoo ti won sese pari yii, ati pe awon osise ajo Fijilante, VSO ti ko din ni 527 lawon to kopa nibe.

Ganzallo so pe lakoko ti idanilekoo naa n lo lowo, lawon rii daju pe awon osise naa gba idanilekoo tawon Batch A ti koko gba nigba ti won se ti won lai pe yii.

Nigba to gboriyin fun ijoba ipinle Ogun, Ganzallo so pe oun dupe lowo ijoba fun atileyin won fun bi won tun se paaro aso won si eyi to dun un won loju, to si yato si eyi ti won ti n lo tele.

Bakan naa lo dupe lowo Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ati Komisana foro Ijoba Ibile ati Oye jije nipinle naa fun ifowosowopo ti won n fun won lati mu ki ise je itewogba lati odo awon araalu.

Bee lo gba awon osise ti won sese gba idanilekoo naa lamoran wi pe ki won rii daju pe won mu awon eko ti won ti gba naa lo, ki won si tun wa ona lati gbogun ti iwa odaran laarin ilu, ati pe ki won ma se ri ara awon gege bii pe won ti koja ofin nitori ti ko seni to koja ofin.

Saaju akoko yii ni Ogbeni Jacob Popogbe to dawon osise ajo naa lekoo lori koko pataki to pe ni "Iwa Ibaje Lagbegbe Wa" je ko di mimo pe ise (poverty) lo fa a ti iwa ibaje ati iwa jegudujera fi po lorileede yii, to si se e gbogun ti bi ifowosowopo ba wa.

Nigba toun naa n soro, Ogbeni Okeowo Gbolahan to je okan lara awon oga agba leka ise ijoba to soju Komisana, Babajide Ojuko nigba to n soro so pe oun mo pe ajo VSO yoo sise won gege bi ise nigba ti won ro won lagbara lodun 2011.

Okeowo je ko di mimo pe VSO ti yato gedengbe si ti tele nitori pe ise ara won ni won n se tele, to je pe se ni won n be won lati wa a sise, nitori ti won ko gba owo osu, sugbon ni bayii, ijoba ti gba ise naa, ti won si ti tewo gba won latari ipa ti won ko nipa oro aabo.

O wa gbawon lamoran wi pe ki won tubo tera mo ise won lati le maa ri oriyin gba latodo awon araalu ati ijoba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI