"Ese
mi jeje, mi o mon on mo" loro ebe to n jade lenu Arabinrin kan ti won
poruko e ni Fatima Balogun, eni odun metalelogbon ti won loo fi foonu pamo sinu
obe to gbe lo fun ale e to wa logba ewon Ibara niluu Abeokuta.
Fatimo |
Kani
obinrin naa mo pe oro naa yoo pada leyin ni, o seese ko ma ronu lati gbe ounje
dani, depodepo wi pe yoo ronu lati fun oko e tele ni foonu.
Gege
bi AWIKONKO se gbo, lojo Wesde ose to koja la gbo pe Fatima pinu lati loo wo
oko e to n fe tele, ko to di pe o ba obinrin miran lo, Ganiyu Ajibode, eni ti
won so pe o ti le losu mefa to ti wa logba ewon naa, leyin ti won fawon esun
kan kan an.
A
gbo pe omo meji ni Fatima bi fun Ganiyu ko to o di pe o loo fe obinrin min in,
ti won si fija tuka lodun merin seyin, latigba naa ni won ko ti ri ara won mo.
Lai
pe la gbo pe Fatima ronu kan baba awon omo e, to si wa a lo, sugbon Iyalenu lo
je nigba to de odo awon ebi e, ti won si so fun un pe o ti wa logba ewon to wa
ni Ibara niluu Abeokuta lati bii osu mefa, toun ko si tii lo yoju sii.
Idi
ni yii ti won ni Fatima fi gbera lati adugbo Fagba, Iju Isaga nipinle Eko to n
gbe, lati loo wo ololufe e tele naa logba ewon pelu ounje aladidun to tun gbe
dani fun.
Ohun
ta a gbo nipe bi Fatima se de odo awon to n so elewon, lo beere Ganiyu ati pe
oun tun fe e gbe oun je fun in, lesekese lawon woda naa ti gba ounje naa lowo
e, ti won si yee wo.
Iyalenu
lo je fun nigba ti won ri foonu ninu kula to bu obe sii, ti won si pariwo e
sita, ko too di pe won pe awon olopaa lati wa a muu nitori ti won so pe nnkan
to se lodi si ofin to de ileese won.
Nigba
toun naa n soro, Fatima so pe asise nla gba a loun se nitori pe kani oun mo pe
asiri maa tu sita ni, oun ko ba ma ti se nnkan to je be e, ati pe oun ko mo pe
nnkan toun se Lodi si ofin.
Fatima
tun so pe bo tile je pe ololufe oun tele naa ko so pe koun mu foonu naa wa,
sugbon lati le maa ba a soro loun se dogbon naa lai mo pe Asiri maa pada tuu.
Bee lo rawo ebe pe ki won dariji oun.
Lati
fidi ise naa mule, Agbenuso fun ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi
nigba to n b'AWIKONKO soro laaro ojo Fraide to koja yi, o so pe atimole awon
olopaa Ibara lo si wa, won ko tii gbe wa sodo awon ni Eleweran lati tubo foro
wa lenu wo.
O
ni leyin tawon ba foro wa a lenu wo tan lawon yoo to o mo boya kawon foju bale
ejo tabi kawon fi sile, sugbon toun mo pe oro e yoo ti ko awon araalu logbon.
No comments:
Post a Comment