Titi
di bi e ti n ka iroyin yi ni igbese lati yan Oba Olota tuntun nijoba ibile
Ado-Odo Ota, ipinle Ogun si n lo lowo, to si di dandan ko pari lojo kerin osu
kejila to n bo lona yii.
Gege
bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi se so, won ni won ko gbodo foro naa
fale rara ati pe ki idile ti ipo Oba naa kan, iyen idile Ijemo/Isolosi loo
forikori, ki won si fikunlukun lati lo o mo eni ti won yo o fa kale gege bi
Oba.
Ninu
atejade ti Komisana to n ri soro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun, Oloye
Babajide Ojuko fi sita se so, o ni igbese naa ko gbodo pe rara nitori pe o ti
fe e pe odun meji bayii ti Olota ana, Oba Moshood Alani Osanyintola Oyede ti
waja lati loo ba awon baba nla e ninu osu karun un odun to koja.
Bakan naa
la tun gbo pe Gomina Amosun tun ti pase pe kawon okoye merin niluu Ota, iyen
Ijana, Oruba, Osi ati Otun naa tun di Oba, iyen Coronet Obas.
No comments:
Post a Comment