Egbe oselu PDP di egbe alawada nipinle Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 13, 2017

Egbe oselu PDP di egbe alawada nipinle Ogun

Titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan, ko tii seni to le so pato ibi ti oro wahala to n sele ninu egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP, eka tipinle Ogun yoo yori si nitori boro wahala naa se ti wa a di egbinrin ote bayii.

Kasamu
Ko si nnkan meji to n fa wahala naa bi ko se ti ipo tani ojulowo alaga egbe oselu naa nipinle Ogun, eyi to je ki egbe naa pin si meji, tawon igun kan fara mo Onimoero Dayo Bayo toun je ti Kasamu, tawon igun keji fara mo Onarebu Sikirulai Ogundele toun je ti Ladi Adebutu ati Gbenga Daniel.

Bo tile je pe ejo tani ojulowo alaga egbe naa si wa ni kootu, ti kootu si ti pase wi pe ki Onimo-Ero Adebayo Adedayo to je ti Seneto Buruji Kasamu si maa se isakoso egbe naa lo titi di odun 2020, sugbon lojo Abameta Satide to koja lo lohun la gbo pe awon igun keji to je ti Ahmed Makarfi pe ipade gbogboogbo, nibi ti won ti seto idibo lati tun fi yan Onarebu Sikirulai Ogundele gege bi alaga egbe naa.

Bayo Dayo
Saaju ki eto idibo naa too bere ni Adedayo ti pariwo sita wi pe irin ajo abewo Makarfi siluu Abeokuta ko lese nile nitori pe ko fi to oun leti, ati pe Makarfi gan an funra e ko mo bi won se n to ile, nitori pe nigba ti ile ejo ti so pe ko se alaga egbe titi di ojo kesan osu kejila, isokan ati ilosiwaju egbe na lo ye ko maa wa, sugbon to je pe nise lo tun n dabaru gbogbo nkan.

Bi won se seto idibo naa tan, ti won kede Ogundele gege bi alaga tuntun fegbe oselu PDP naa nipinle Ogun ni Bayo Dayo ti so pe nise ni won n tan ara won je, nitori pe ko seni to le gbe idajo ile ejo to wa nile segbe, lai je pe ile ejo min in tun soro le e lori.

Nigba to maa di aaro lojo Aje Monde ose to koja la gbo pe Ogundele lewaju awon oloye egbe naa ti won so pe won sese dibo yan lewaju awon omo egbe to je ti won loo si olu ileese naa to wa ni lagbegbe NNPC niluu Abeokuta lati loo so pe awon ti de lati gba a.

Ogundele
Nibe ni Ogundele ti bawon oniroyin soro wi pe gbigba tawon wa a gba ileese naa pada lowo awon to wa tele kii se nipa tija tabi jagidijagan, bi ko se nipa ase lati odo awon olori won niluu Abuja, to si tun fesun kan awon to n sakoso e tele wi pe nkan to to milionu marun un naira ni won ti baje nibe.

Bi iroyin yi se te Bayo Dayo atawon eeyan lowo lawon naa ti gbera lati loo wo nkan to n sele nibe, iyalenu lo je nigba tawon naa tun so pe awon egbe alatako ti won n da ara won laamu ti ko awon toogi wa ba ile egbe naa je, ti won tun ji awon eru gbe nibe, eyi lo fa a ti won fi ko awon kan lara awon toogi metadinlogun ti won ba nibe loo siwaju adajo lojo keji, ti won si fesun odaran kan won..

Dayo tun fesun kan komisana olopaa ipnle Ogun, Ahmed Iliyasu wi pe o ti gbabodi nitori pe gbogbo bi nnkan se n lo ninu egbe naa loun fi n to o leti, toun tun ko awon iwe eri tawon gba ni kootu fun un lati le mo wi pe awon gan an ni ase egbe naa wa lowo e, to si gbawon kan laaye lati loo ja ofiisi naa leyin.

Makarfi
Bayo Dayo tun so pe Ahmed Makarfi ko ni ipinu gidi fegbenaa, ati pe oun gan an nigi leyin ogba to n da egbe ru, nitori pe kaka ko lo ipo e lati yanju aawo to wa ninu egbe, erongba lati di aare orileede Naijria lo wa lokan e, leyi ti ko le ri. O ni kii se ipinle Ogun nikan ni egbe oselu PDP ti ni wahala, bee lo wa ni Adamawa, Kwara, Oyo, Osun Ondo, Ekiti ati Eko ti ko si ti niyanju titi di akoko yii.

Bee lo tun fesun kan gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel to tun je adije sipo alaga egbe naa lapapo wi pe oun naa pelu awon to n da egbe naa ru, to si tun so pe apoti ibo alaga egbe naa to loun fe e gbe, bi eni to n tan ara e je ni, nitori pe to ba a gbe apoti kanselo ni ijoba ibile e ni Sagamu, ko lee wole.

O ni eni to je pe ko tii bo ninu esun ikowoje ti ajo EFCC fi kan an lati odun 2011, lo maa wa gbe apoti ko wole, ko see se. O tun so pe alabagebe ni Daniel latari bo se n sa kuro ninu egbe kan bo si egbe min, nitori pe o ku die ko pari isejoba e lodun 2011 lo loo da egbe PPN sile, to tun kuro nibe lo sinu egbe Labour, ko too di pe o pada wa segbe PDP.

OGD
O wa so pe awon ko ni ye  e gbe ara won lo sile ejo nitori pe oun gan an lawon gbojule to maa bawon ri owo awon to ba fe e ba egbe won je wole. 

Daniel nigba to n fesi soro naa so pe bo tile je pe oun ko fe e soro tele lori esun oun to wa nile ejo, nitori pe ifisun (persecution) lasan ni, toun si ti yoju si kootu fun igba ogoji laarin odun meje toun ti wa lenu e. O ni ko seni to le di oun lowo lati dupo alaga egbe naa lapapo, ko da ti esun toun n je nile ejo gan an ko le da oun duro, nitori pe ile ejo ko tii fidi e mule pe looto loun jebi awon esun ti won fi kan oun, ati pe atamo oro lawon to n tako oun kaakiri n wa, eyi ti ko le seese fun.

Titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan la gbo pe awon eeyan naa si wa nilu Abuja nibi ti won ipade ti n lo lowo lati tun le mo ona min ti won tun fe e gba yo, tawon eeyan si n so pe egbe naa ti wa a di egbe alawada bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI