Oludasile gbajumo soosi Treasure House of God to wa niluu Abeokuta, Pasito Seye Senfuye ti so pe ebun repete lorisirisi lo ti wa nile fawon alaini fun ti ayeye odun keresimesi to n bo lona ninu osu kejila ti a fe e mu yi.
Alakoso foro iroyin fun ijo naa, Ogbeni Adeniyi Adeloye lo soro naa lakoko yo n gba enu Pasito Senfuye soro lai pe yi niluu Abeokuta wi pe eto naa je ti olodoodun, ati pe o ti wa ninu ilana ti Ijo naa ti la sile latigba ti won ti da a sile.
Adeniyi so pe ona ara ni eto fi fawon alaini lebun odun naa yoo gba waye lodun yi nitori pe kii se awon alaini to wa ninu ijo naa ni eto todun yi wa fun, gbogbo awon alaini to wa ninu ijo naa ati agbegbe e ni won yoo je anfaani e, to fi mo gbogbo awon akoroyin to wa nipinle Ogun.
O tun so pe yato sawon alaini to wa lagbegbe ijo naa, awon ti won ba rii pe atije ko rorun fun won niluu Abeokuta, ipinle Ogun, to fi mo awon alaini lorileede Naijiria ni won yoo tun je anfaani e bakan naa.
Adeniyi so pe kii se pe won deede gbe eto naa kale, bi ko se iwa aanu ti oludasile ijo naa, Pasito Senfuye to tun ti figba kan je akowe owo (Accountant General) fun ijoba ipinle Ogun nigba kan ri naa ni, ati pe ko fi oro eleyameya se nitori to gba pe oro eleyameya ko nitewogba lowo Olorun.
AWIKONKO gbo pe opolopo baagi iresi, adiye odun atawon ebun lorisirisi lo ti wa nile lati pin fawon eeyan bayii fun ti ayeye odun ta a fe mu naa.
No comments:
Post a Comment