E je ka gba alaafia ati isokan laaye - FUNAAB - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 21, 2017

E je ka gba alaafia ati isokan laaye - FUNAAB

Giwa tuntun fun ileewe to n kekoo nipa imo ogbin, Federal University of Agriculture (FUNAAB), Abeokuta, Ojogbon Kolawole Salako ti rawo ebe sawon osise ileewe naa atawon ara agbegbe Alabata wi pe ki won gba isokan ati alaafia laaye lasiko toun di Giwa ileewe naa.

Ojogbon Salako
Ojogbon Kolawole Salako lo rawo ebe yi lojo Eti Fraide ose to koja nibi eto Adura awon musulumi, iyen Jumat ti won se ninu mosalasi ati lojo Aiku Sande to koja yi nile ijosin ileewe naa, iyen Chapel of Grace.

O so pe o se pataki kawon elesin mejeeji fi ife ati isokan han si ara won, paapaa osise ileewe naa atawon to gba won sori ile won.

Salako so pe oun kii fi oro eleyameya se, paapaa lori oro esin, sugbon toun maa n gba awon eeyan laaye latari bi won ba se fi ife ati oyaya han si ise ti won ba n se.

Nigba to n gbawon eeyan lamoran, o ni ki won maa fi gbogbo nkan to ba n lo, gala edun okan won tabi omin in to oun leti, pelu ileri wi pe oun setan lati teti gbo gbogbo alaye lai beru tabi sojusaaju enikeni.

Salako nigba to n gbawon akekoo lamoran so pe ki won ri daju pe won mo nkan ti won n se, ki won si maa bowo fawon alase paapaa awon ti owo ba to si nileewe naa, ki won si tun rii daju pe won n fi oro awon to ba fi ilokulo lo.won to awon alase leti lati le tete gbe igbese le e lori.

Bakan naa lo dupe lowo awon agbarijo awon elesin musulumi fun ifowosowopo won lasiko ti won yan an, bee lo so pe inu oun yoo dun ti won ba tubo n satileyin foun atawon alase ileewe naa pelu adura won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI