Titi
di bi e ti n ka iroyin yi lowo ni ileewe Osun State College of Education to wa
nilu Ila Orangun, nipinle Osun si n gbona janjan lowo latari bawon olopaa se pa
awon akekoo meji ileewe naa lojo Aje Monde ana.
Gege
b'AWIKONKO se gbo, won ni awon akekoo ileewe giga kaakiri ipinle Osun ni won
dide ifehonuhan alaafia sijoba lati tako ipinu ti won sese se nipa owo ileewe
won ti won tun fowo kun, eyi ti ko dun sawon akekoo naa ninu.
AWIKONKO
gbo pe ikorita kan to gbajumo, iyen ikorita Olaiya lawon akekoo naa ti ko ara
won jo, ko too di pe won bere iwode naa. Agbegbe Gbongan si Osogbo la gbo pe
awon akekoo naa gba, ti won si n korin bu ijoba ipinle naa wi pe ko se daadaa
nipa owo ileewe won ti won tun fowo kun.
A
gbo pe bawon olopaa se ri won, ni won ti yin ibon tajutaju (tear gas) si won
loju, ti won tun yin in fun Azeez to je akekoo Ila Orangun leka ikekoo Oyinbo,
bee ni won tun fo kini naa mo Femi lori, ti won si sare gbe won lo sile iwosan
fun itoju oju won.
Ohun
ta a gbo ni pe osibitu ti won koko gbe Femi ni won ti so pe awon ko le se e, to
fa a ti won fi pada gbe e lo si osibitu olukoni ti Obafemi Awolowo (Teaching
Hospital) nibi to ti n gba itoju lowo.
Lara
awon akekoo nileewe gbogbonise ti Iree, iyen Osun State Polytechnic so pe
egberun merinlelogbon (#34,000) lowo ileewe tawon n san tele, sugbon ti won ti
so pe egberun marundinlaadorin (#65,000) naira lawon yoo tun maa san bayii.
Se
lawon akekoo naa kominu lori ipinu ijoba ipinle Osun pelu igbese naa, ati pe
won tun so pe ipinu naa ko bojumu latari bijoba tun se je awon obi won to n
sise labe ijoba naa lowo osu, ti won ko si tun fowo kun owo osu won.
Ogbeni
Saheed Afolabi to je pe igbakeji oludari egbe akekoo nile Yoruba nigba yo n
jeri soro naa so pe iwa tawon olopaa naa ku die kaato nitori pe nise lo ye ki
won wa ona min in lati da si oro naa, di pe ki won yinbon tawon tajutaju lu
awon akekoo to je pe eto won ni won n ja fun.
Nigba
to n tako esun awon akekoo naa, Komisana foro iroyin ati bo se n lo nipinle
Osun, Ogbeni Adelani Baderinwa so pe aheso ti ko lese nile lasan ni won n so pe
ijoba fowo kun owo ileewe nipinle naa.
O
lawon to sese fe e wole sawon ileewe giga kaakiri ipinle naa lo je pe won yoo
san awon owo kan tijoba sese se ipinu e jade sita ati pe ko kan awon to ti n
kekoo lowo.
O
wa tun je ko di mimo pe ijoba Ogbeni Aregbesola yo je gomina won lo din owo
awon ileewe ku si iye ti won n san tele nigba to gba opa ase gege bi gomina
lodun 2011.
No comments:
Post a Comment