Seneto
Buruji Kasamu to n soju ekun Ogun East nile igbimo asofin agba niluu Abuja ti
so pe ajalu nla ni eni to je gege bi alaga egbe oselu PDP lapapo, iyen Oloye
Ahmed Makarfi je fegbe oselu naa.
Ninu
atejade to fi sita lojo Aiku Sande to koja yi, leyin ti egbe oselu PDP se ipo
keta nibi eto idibo naa lo ti so pe "O foju han gbangba wi pe Makarfi
atawon eeyan ti ko oriburuku wonu egbe oselu PDP."
O
so pe "Makarfi atawon eeyan de sinu egbe oselu PDP gege bii Mesaya
(Messiah) tawon ti n reti, sugbon to je pe awon gan an lo yi nkan pada, to si n
pa egbe oselu naa run latari ona eburu ati iwa imotaraeni nikan ti won n ba
kaakiri."
Kasamu
to tun je okan pataki ninu egbe oselu naa nile Yoruba soro yi lati fi tako
Makarfi latari bi egbe oselu PDP se padanu nibi eto idibo to aaye nipinle
Anambra lojo Abameta Satide to koja yii, to si je pe adije latinu egbe oselu
APGA, Willie Obiano lo jawe olubori.
No comments:
Post a Comment