Aarun opolo lo n fa iwa ipa lawujo wa - Adebowale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 27, 2017

Aarun opolo lo n fa iwa ipa lawujo wa - Adebowale

Olori awon dokita nile iwosan ti won ti n toju aarun opolo, iyen Provost, Neuro Psychiatric Hospital, Aro niluu Abeokuta, Dokita Olaoluwa Adebowale ti so pe aarun opolo lo n fa iwa ipa ati jagidijagan lawujo wa lakoko yi, eyi to mu kawon eeyan maa se ara won nisekuse.

Adebowale soro yi lakoko to n dawon eeyan lekoo lori akole pataki ti won pe ni "Iwa ipa ati adojuko agbegbe; ipalara fawon obinrin" (Domestic Violence and Societal Challenges for Women) eyi tegbe awon oniroyin obinrin lorileede Naijiria, eka tipinle Ogun, National Association of Women Journalists (NAWOJ) sagbateru e ninu gbongan awon oniroyin to wa ni Oke-Ilewo, Abeokuta.

Ninu oro e lo ti so pe bi a ba wo nkan to n sele lorileede yii, opo awon iwa buruku lo ti kun awujo wa, to si fa kawon okunrin maa lo awon obinrin paapaa awon omodebinrin nilokulo.

O tenumo on pe eyi to buru ju ni iwa ifipa banilopo to mu ki awon agbalagba maa ba egbe omo-omo sun lai ronu atubotan e.

Bee naa lo tun so pe awon okunrin a tun maa fogbon gba owo lowo awon obinrin won, paapaa kawon okunrin tun kan an nipa wi pe awon obinrin ni ki won maa gbe bukata idile.

Bee naa lo so nipa ona tawon obinrin naa fi n je awon okunrin niya, o ni orisirisi ona lo wa tawon obinrin fi n je awon okunrin niyanju, sugbon eyi to buru ju nibe ni ti ibalopo.

Adebowale tun so pe awon obinrin min in wa to je pe won a tun yowo ese ti awon oko won, ati pe opo awon obinrin ni won ti seku pa awon oko won nigba ti won ba ni gbolohun aso.

O fi kun un pe eyi gan an lo ye kawon olopaa maa foju si, sugbon di pe bee, obinrin naa ni won a tun gbe leyin e pe nkan to ri lasiko toun ati oko e ni gbonmisi-omioto lo fi daabo bo ara e.

Nigba to n soro lori awon nkan to n sokunfa iwa naa, o ni awon nkan bii iriri, ilara, aigbo ara eni ye, aile te ara eni lorun nipa ibalopo atawon min in lo n fa a.

O so pe iwadii fi ye wa pe ida ogorun ninu awon to n huwa buruku lo je won ni aarun opolo lona kan abi omin in, to si soro fawon eeyan lati tete mo.

Saaju akoko yi ni alaga egbe NAWOJ naa, Arabinrin Remi Adebiyi ti so nipa idi pataki ti won fi yan akole naa fun ayeye ose awon oniroyin obinrin todun yi. O so pe nkan elege lawon obinrin je, to si ye kawon okunrin maa gbe won gege bi eyin oju ti nkankan ko gbodo se.

Ninu oro ti e, alaga egbe awon oniroyin lapapo nipinle Ogun, Komureedi Wole Sokunbi naa lo ti dupe lowo Dokita Adebowale fun bo se pon egbe NAWOJ naa le lati wa a bawon soro nipa akole ti won yan naa.

Sokunbi tenumo on pe gbogbo iwa ipa ati sise obinrin nisekuse lo je nkan to ye kawon eeyan tete sabojuto e latari nkan to n sele lawon awujo wa lorileede yii ati kaakiri agbaye.

Bakan naa lo tun dupe lowo egbe NAWOJ fun bi won se mu akole naa nitori pe bi won ko ba tete mojuto, o le se maa tesiwaju lo.

Lara awon to tun wa nibi eto naa ni; Ogbeni Adekunle Adebiyi to je oko alaga egbe NAWOJ; Komureedi Soji Amosu, akowe egbe akoroyin nipinle Ogun; Ogbeni Dimeji Kayode Adedeji to je akoroyin fun iwe iroyin Premium Times; Abiodun Taiwo; Kunle Olayeni.

Awon min in ni Ogbeni Niyi to je alaga egbe akoroyin ti Federated Chapel; awon egbe akoroyin Correspondent Chapel; to fi mo awon osise ile iwosan FMC to sayewo ofe fawon eeyan, ati asoju eso oju popona, iyen TRACE, Arabinrin Morolake Filani, atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI