Bo
tile je pe oludamoran pataki fun olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, Ogbeni
Waheed Akinola ti so pe ko si ooto oro ninu aheso ti won n gbe kaakiri nipa oga
e, Omoba Suraju Ishola Adekunbi wi pe awon kan fe e dite lati yoo nipo, ati pe
nitori e lo se gbe opa ase ile igbimo asofin naa pamo, sibe ohun tawon eeyan n
so ni pe iro nla ni won n pa.
Gege
b'AWIKONKO se gbo, won ni afaimo ni ki wahala maa be sile nile igbimo asofin
tipinle Ogun nitori bi won se lawon asofin kan se n gbero lati yo olori won
naa, iyen Suraju Adekunbi nipo.
Ohun
ta gbo ni pe won ni Okunrin olori ile igbimo asofin naa ti n fura pe nnkan kan
fee sele idi niyii to fi loo gbe opa ase ile igbimo naa pamo sile ijoba, ti ko
je kenikeni mo ibi to gbe e sii.
Won
ni se lokunrin naa loo gbe opa naa pamo kawon omo ile igbimo asofin naa maa ba
dite gbajoba mo on lowo, ko to ti irinajo to loo siluu London to sese de yii
de.
Lose
to lo lohun ni Adekunbi rin irinajo loo siluu London nibi apero kan tawon
omo ile Yewa sagbekale e, paapaa lati tun fi wa ojurere awon eeyan naa
fun ti ipinu oselu e lati dupo Gomina lodun 2019.
A
gbo pe anfaani naa lawon ti ko gba ti Adekunbi naa fee lo lati fi le kuro nipo
sugbon toun naa tete fura pe o seese ki omi teyin wogbin oun lenu toun ko ba
tete dogbon soro ara oun.
Iroyin
to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe lati bi osu meloo kan seyin lawon omo ile
igbimo asofin ipinle Ogun ti pin si meji, metala, metala ni won mu ara won.
Idi
won ni won se fee yo okunrin naa ko ju bi won se so pe ibasepo pelu gomina
Amosun lenu ojo meta yi n fa akoba nla fun won.
Iwadii
tun fi ye wa pe nitori olori ile igbimo asofin naa ko fokan tan awon omo abe
yii lo mu ko pinu lati loo gbe opa ase naa pamo sile ijoba.
AWIKONKO
gbo pe bi Suraju Adekunbi se de lati ilu London lo ti sare loo gbe opa ase naa
jade sita lahamo to gbe e pamo si ko too lo, eyi gan ni won loo fun oludamoran
pataki e yi, Ogbeni Waheed lenu oro lati tako iroyin naa pe ko si nkan to jo
be.
No comments:
Post a Comment