Ki ise eto aabo ba tubo le kesejare sii nipinle Ogun, ajo
Fijilante ojulalakanfinsori ipinle Ogun, Vigilante Service of Ogun state (VSO)
ti rawo ebe sijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun lati ran won lowo ki
ise eto aabo tun le gbe peeli soke sii.
Soji Ganzallo |
Nibi ayeye eto ibura fawon oloye ekun Egba, iyen Egba
Zone tuntun ti won sese yan lati rii daju pe emi ati dukia awon araalu wa bo se ye ko wa, ko ma si si wahala kankan to jomo iwa odaran mo.
Ayeye naa waye ninu ogba ileese won tuntun to wa ni Arakanga, ijoba ibile
Abeokuta North lojo Abameta Satide oni yii, iyen ojo kerinla osu kewaa.
Gege
bi a se gbo, won so pe ekun naa ko ni awon irin se ti won le maa lo, eyi to le
mu ki ise won rorun lona igbalode lati le maa daabo bo emi ati dukia awon
araalu.
Lara awon oloye
tuntun ekun Egba naa ni; Salisu Najeemdeen to ke Commander; Ewuoso Sakiru to je
igbakeji Commander; Akinwunmi Ismail toun je Administrative; Bode Kusimo toun
ni Operation; Osanyinpeju Adewole to wa Finance; Omolaja Bankole toun je
Operation II.
Awon min in ni
Ogundimu Adebisi toun je Logistics; Akinola Olufunmilayo toun wa ni Anti Human
Trafficking; Taiwo Adesegun to je Welfare; Oladipupo Olaifa to wa ni
Intelligence ati Mayoade Samuel toun je Provost.
Lara
awon nnkan ti won so pe o n je won niya ni moto ati okada ti won le maa fi
sise, ibon, ofiisi atawon irinse min in ni won so pe awon n foju sona fun ijoba
ibile Abeokuta North paapaa ijoba ipinle Ogun.
Igbakeji
alaga ijoba, to tun je oga ajo ipawo wole nijoba ibile naa, Isiaq Bada to soju
fun oga e gboriyin fun ajo naa fun ise ti won n se laarin ilu.
Bada
so pe bo tile je pe awon ti n da si oro naa lateyinwa nitori pe ijoba ibile naa
lo pese ofiisi tuntun ti won n lo naa fun won, si be, awon ko dawo duro nitori
tawon mo riri ati ipa ise ti won n se fun won laarin ilu, paapaa nijoba ibile
naa.
O wa
ro awon oloye egbe tuntun naa pe ki won ma ri ara won gege bi oga, sugbon ki
won ri ara won gege bi eni to wa sin ilu e pelu ife to ni sii, ki won si rii
daju pe won ko fi oro eleseyameya sise ti won yan won fun.
Nigba
to n soro, adari pata fun ajo naa nipinle Ogun, Ogbeni Olusoji Ganzallo nigba
to n ba oniroyin wa soro, o so pe bo tile je pe awon ko duro ninu ise eto aabo
ilu, tawon sii n ri daju pe emi ati dukia awon araalu je awon logun, sibe awon
si nilo ki ijoba tubo pese awon irinse to joju fawon.
Ganzallo
so pe ki awon to o pinu lati bura fawon oloye ekun Egba tuntun naa lawon ti n
ri ipa ti won n ko laarin ilu lati rii daju pe ise aabo ilu tubo kese jare, eyi
lo foun lokan bale pe won a sise ti won gbe le won lowo bo se to ati bo se ye.
adari tuntun |
Sibe,
adari naa gbawon oloye naa lamoran pe ki won ma se ri ara won gege bi eni to ti
de ibi ti won fe e de, sugbon ki won ri ara won gege bi eni to setan lati sin
ilu e tokantokan nitori orin ogo ipinle Ogun to so pe "ise ya", won
ko si gbodo duro.
Nigba
toun naa n soro, adari eka ekun Egba Zone, Ogbeni Najeem Salisu Alao so pe inu
oun dun latari bi eto naa se waye, ati pe nnkan toun ti n foju sona fun lati
ojo pipe wa ni, nitori toun ti sise sin ajo naa tokantokan.
O ni
ipinu toun ni gege bi adari tuntun lekun naa pelu ife toun ni si ipinle oun,
loun yoo se rii daju pe ise n tesiwaju ni gbogbo igba.
Salisu
wa rawo ebe sijoba ipinle Ogun ati ijoba ibile lati tubo ran awon lowo, nitori
tawon nilo irinse bii moto, okada atawon nnkan to le mu ki ise aabo tubo le
rorun fawon lati le se aseyori sii.
Saaju
akoko yi ni asoju Gomina
Ibikunle Amosun, Ogbeni Q.O Usman dupe lowo ajo VSO fun ipa ati akitiyan ti won
n ko nipa eto aabo nipinle Ogun, pelu bo se je pe awon nikan ni ijoba fowo si
gege bi ojulowo ajo Fijilante.
O loun yoo jise
tawon eeyan naa ran oun sijoba, toun si mo pe ijoba yoo gbe igbese to ye le e
lori nitori pe gomina to nife araalu lawon ni nipinle Ogun, ti ko si ni doju ti
won.
No comments:
Post a Comment