Ko si iroyin meji to tun n lo kaakiri agbaye
bayii bi ko se ti iroyin ojo ibi aadota odun ti ilu mon on ka olorin Fuji nni,
Alaaji Alabi Ajibola topo mo si Pasuma, tawon eeyan lagbole orin tun mo si
Oganla 1 to fee waye lojo ketadinlogbon osu yii (November 27, 2017).
Eyi gan an lo fa ti won fi n pe ede tuntun
bayii pe PASO ti WASO, iyen ni pe Pasuma ti pe aadota odun, gege bi e se mo pe
Wazobia lawon eya ile Awusa (Hausa) orileede yii maa n pe fifthy (50) ti Yoruba
n pe ni aadota, eyi lo fa ti won fi n so pe Paso ti Waso.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won
so pe ose yi gan an, iyen oni ojo ketala ni won yoo bere eto naa pelu idije ere
boolu alafese gba to maa waye laarin awon egbe ololufe Pasuma, iyen Pasuma Fans
Club eka tipinle Ogun ati ipinle Ekoo.
A gbo pe aso (T-Shirt) peluu Fila ti wa nile
fawon ololufe to ba fe e ra, bee naa ni Ankara ti wa nile fawon to ba nife si,
nitori taa gbo pe eni ti ko ba wo aso lojo naa, ko ni lanfaani lati wole sinu
gbongan ti won fe e lo lojo naa.
Lara awon to n bo lojo naa ni Gomina ipinle
Ekoo, Akinwunmi Ambode atawon oloselu kaakiri orileede yi, to fi mo awon eeyan
jankan-jankan lawujo, ati kaakiri agbaye.
AWIKONKO tun gbo pe, ko too di ojo
ketadinlogun osu ni oka lara awon ololufe Oganla Fuji, iyen alase ileese igbafe
Ibray Seaside Resort to wa ni Ibasa Waterfront Satellite Island, Satellite
Town, ipinle Ekoo naa yoo sagbekale eto ayeye ojo ibi fun Pasuma, eyi tawon
eeyan yoo fi egberun marun naira wole sinu gbongan ti won ti fee se lojo naa.
Aago mejila osan ni won so pe eto naa yoo
bere pelu eto olokan-o-jokan ti won ti la kale fojo naa, iyen ojo
kerindinlogbon (November 26th). Lara awon ti won so pe won yoo mu
ayeye ojo naa larinrin ni gbajumo oni tiata nni, Odunlade Adekola, atawon
olorin bii Small Doctor, Destiny Boi atawon min in.
Bee la gbo pe awon bii Alfa Kayeefi, Pencil
G, Alawiye, Ogagun SK atawon min in derin pa awon alejo lojo naa.
No comments:
Post a Comment