Pasito Jeremiah atawon merin to n feeyan rubo ti foju bale ejo o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 24, 2017

Pasito Jeremiah atawon merin to n feeyan rubo ti foju bale ejo o

Adajo ileepo Majisireeti to fikale siluu Ota, Onidajo B.B Adebowale ti pase fawon olopaa wi pe ki won loo fi Pasito Jeremiah Ademola atawon babalawo ti won jo n fi eeyan rubo pamo si ogba ewon ojo marundinlogbon osu yii (October 25), iyen ojo Wesde to n bo yii.

Be o ba gbagbe, lojo ketala osu kejo (August 13) lasiri Pasito Jeremiah Ademola tu sawon araalu lowo lagbegbe Egan, Iyana Iyesi, Ota, ipinle Ogun leyin ti owo te Samuel Babatunde to ji omo meji gbe, to si so pe ki won se oun jeje nigba naa, nitori pe o lawon to ran oun.

Asiko naa ni owo olopaa FSARS tele Babatunde loo si soosi Kerubu ati Serafu, Itedo Isinmi, Ayo Parish, eyi ti Pasito Jeremiah je oludari e lakoko ti won n se isin lowo laaro Sande, ti won si hu ileele inu soosi nibi ti won ti ba awon nnkan to jo eya ara eeyan nibe.

E ma gbagbe: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/egbe-egbaga-ko-ile-iwosan-fawon-ara.html 

Eyi lo fa a ti Pasito naa fi jewo wi pe oun tun lawon to n ba oun sise, ti babalawo naa si wa lara won, ko too di pe owo te Obaniyi Michael ati Haruna Afolabi laaro ojo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI