Orin
ope lawon araadugbo Fajol, Obantoko mu senu lai pe yii nigba ti asiri
odomokunrin kan, Nureni Odejobi tawon eeyan tun mo si Kugu, ti won loun ni
olori awon ogbologbo adigunjale to n pawon araalu lekun jaye.
Nureni Kugu |
Gege
b'AWIKONKO se gbo, ojo kesan osu yi lasiri e tu sita leyin ti won loo lo fo
gilaasi moto okunrin kan, Oluyemi Akala to si ko gbogbo eru to wa ninu e
salo, sugbon tasiri e si pada tu sita.
Ohun
ta a gbo ni pe, okunrin kan ti won n pe ni Abbey Bencash ti won lo maa n saye
fawon eeyan sese de latilu oyinbo, to si se faaji fawon eeyan lojo kejo
osu yii nibi ti Kugu naa wa.
Bencash
yi la gbo pe o ranse pe Oluyemi toun n ta oti wi pe ko loo ko oti sii wa, nigba
to si maa pada de be lo sakiyesi pe oti ti won muu ti poju, eyi ti ko je ko ko
oti naa bo sile ninu moto titi ti won fi setan lale ojo naa.
AWIKONKO
gbo pe nigba tonikaluku won n gba ile won lo ni moto Oluyemi taku, to si paaki
e segbe kan lero wi pe oun yoo pe mekaniiki lati wa wo nnkan to n se e lojo
keji, lai mo pe Kugu n so o.
A
gbo pe bi Oluyemi se lo tan, ni Kugu atawon ore e meji kan, Yaradua ati Fajol
lo sidi moto naa, ti won si fo gilaasi e, ti won ko awon oti naa pelu awon eru
min in, to fi mo batiri ati redio inu moto naa salo.
Ohun
taa gbo nipe awon eeyan ni won ranse pe Oluyemi laaro ojo keji pe won ti fo
gilaasi moto e, toun naa si tete gbera lati loo wo o, iyalenu ni won loo je
fun, to si fibinu loo foro naa to Abbey Bencash leti.
Abbey
Bencash ni won loo fura pe o seese ko je pe Kugu lo sise naa nitori to so pe
oun ti n gbo iroyin pe awon adigunjale n dawon eeyan laamu ladugbo naa, eyi ti
Kugu naa wa lara won.
Lesekese
ni won so pe won ti loo ka Kugu mole lati foro wa a lenu wo, sugbon Awon oro to
n so ni won loo mu ifura dani, ti won lawon eeyan bii mewaa tun jade lati jerii
tako o.
Moto naa re e |
Iya
agbalagba to n ta ounje ladugbo naa, okunrin Ahusa to n ta Suya ati aso gini
(Guinea), odomokunrin to n ta komputa ati okunrin kan toun se batiri saja
(battery charger) la gbo pe Kugu ti ja lole, ti won si b'AWIKONKO soro.
Won
ni osu to koja lo jale kan, ti won muu lo si tesan olopaa to wa ni Obantoko
nibi ti won ti pada fi sile pelu ajosepo e pelu awon olopaa naa.
A
gbo pe bo tile je pe ko koko jewoo, sugbon bi won se n muu wonu ogba awon SARS
to wa ni Magbon lo ti bere sii bebe pe ki won se oun jeje, ati pe awon meta
lawon jo n sise naa.
Ojo
keta ni won so pe awon SARS lo ye ile Kugu wo nibi ti won ti ba ibon ilewo kan,
ero komputa alagbeka atawon eru min in to jo eru ole nibe.
Lati
fidi oro naa mule, agbenuso fun ileese olopaa nipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi
nigba to n bakoroyin wa soro laaro ojo Tosde ose to koja, o loun ko tii gbo
nipa isele naa, sugbon toun yoo sewadi nigba toun ba de ibi ise.
Ohun
ta a gbo ni pe awon SARS ti gbe Kugu lo si ogba awon elewon to wa ni Oba, nibi
to ti n gbategun itura, bee ni won ni iwadii si n lo lowo lori bi won se maa mu
Yaradua ati Fajol to na papa bora.
No comments:
Post a Comment