Osu kan gbako ki iwe itan "Yoruba Ni Tooto" jade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 16, 2017

Osu kan gbako ki iwe itan "Yoruba Ni Tooto" jade

Bo ya le mo pe bi e se n ka iroyin yi lowo ni oni ojo Aje Monde, ojo kerindinlogun lo pe osu kan geerege ti iwe tuntun tawon Ojogbon kaakiri ileewe giga tawon olukoni iyen Federal Colleges of Education kaakiri orileede Naijiria, to fi mo awon Ojogbon to mo nipa isedale ati itan Yoruba fowo si, iyen YORUBA NI TOOTO yoo jade sita.

Yoruba Ni Tooto
Yato si awon Ojogbon leka eto eko lorileeede yi, awon oloselu atawon agbaagba to le so nipa itan ile Yoruba naa bu owo lu iwe Yoruba Ni Tooto, ti won si ti n gbaradi fun ojo kerindinlogun osu kokanla to n bo yi, iyen November 16th, 2017 ti won fe e sayeye ifilole iwe naa ninu gbongan ileewe awon oniroyin, Nigeria Institute of Journalism (NIJ), to wa ni Ogba ipinle Eko, aago mejila osan layeye naa yoo bere.

Iroyin tuntun to tun sese te AWIKONKO lowo je ko di mimo pe olootu iwe Yoruba Ni Tooto, Ogbeni Oyekunle Babarinde to tun je olootu (Editor) iwe iroyin Alariya Oodua, iyen iwe iroyin to n gbe Ewa ati Asa Yoruba laruge lose-ose ko iwe naa ni iranti awon abiyamo gidi, iyen awon iya awon otokulu lorileeede yi.

Awon ti Ogbeni Oyekunle Babarinde ko iwe naa ni iranti won ni; Oloogbe Arabinrin HID Awolowo; iya Oloye Olusegun Obasanjo; iya Asiwaju Bola Ahmed Tinubu; iya Ogbeni Rauf Aregbesola; iya Ogbeni Femi Adesina to je agbenuso fun Aare Muhammad Buhari.

Iwe ipe sibi ayeye naa
Awon to ku ni; iya Ooni tile Ile-Ife, Oba Enitan Ogunwusi; iya Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi; iya Olubadan tiluu Ibadan, Oba Saliu Adetunji; iya igbakeji gomina ipinle Osun tele, Seneto Iyiola Omisore ati iya Otunba Gani Adams to je olori egbe OPC, to tun je Aare Ona Kakanfo tuntun ti won seese yan.

AWIKONKO tun gbo pe gbogbo eto lo ti to fun ayeye ikojade iwe tuntun naa, lara awon eto ti won ti la kale fun ayeye onibeta naa ni won so pe won ti fee fawon to ti ko ipa ribiribi lorileeede yi ni awoodu, ti won yoo tun sayeye nla fun Ogbeni Oyekunle Babarinde.

Ni bayii, iroyin to tun te AWIKONKO leti je ko di mimo aso funfun lo maa gba eye lojo naa, nitori pe oun gan an ni won mu fawon alejo to n bo lati wo. Bo tile je pe kii se pe eni ti ko ba ti wo aso funfun ko nii wole sinu gbongan lojo naa, sugbon aso naa to je pe oun lawon eeyan nla-nla feran lati maa wo lo je ki won pinu pe aso funfun ni won pe fawon alejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI