Orileede Naijiria kun oju osuwon lati ni ounje ajeseku – FUNAAB - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 17, 2017

Orileede Naijiria kun oju osuwon lati ni ounje ajeseku – FUNAAB

Adele giwa fun ileewe giga ti ise ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB), Ojogbon Ololade Enikuomehin ti je ko di mimo pe o seese ki orileede Naijiria ni atito ati aniseku ounje, eyi ti yoo po jaburata bi ijoba orileede yi ba se awon nnkan to ye ki won se, nipa agbekale awon ilana ti yoo mu ki eto ise agbe ati ogbin dagbasoke.

Ojogbon Enikuomehin lo soro yi nibi ipade awon oniroyin ti won se ninu gbongan ile igbimo asofin (Senate Chamber) to wa ninu ogba ileewe naa ni imurasile fun ayeye ikekoo gboye awon akekoo won, eyi to je eleeketalelogun, ikerinlelogun ati ikeedogbon iru e, ti won fe e se papo lojo Abameta Satide to n bo yii, iyen ojo kokanlelogun osu kewaa.

O so pe pelu awon iwadii toun ti se atawon nnkan toun ti ri kaakiri, orileede Naijiria kun oju osuwon lati bo ara e lai je pe won ko ounje wole lati orileede min in.

Enikuomehin, tesiwaju pe nnkan to fa ti orileede Naijiria ko tii se wa nibi to ye ko wa ni bi awon kudie-kudie ti ko je ki ise agbe ati ogbin gbooro, iyen nipa bi ijoba se ko lati se awon iwadii ijinle nipa awon ohun ti yoo mu ki ise agbe dagba soke, ti yoo tun fun won lanfaani lati wa lara awon orileede to n lewaju nipa tita ounje sawon orileede kaakiri agbaye.

Adele giwa naa kaniminu pupo lori akitiyan ati awon ohun amuye ati amusoro ti fasiti naa ni pelu awon imo ijinle ti won ti se nipa awon nnkan ogin ati eranko, tawon ojogbon si n gbosuba kare fun won, sugbon ti ijoba ko fun won ni koriya lati je ki awon ise iwadii won yo sita gbangba, eyi to si n nu ifaseyin ba idagbasoke ounje.

O fi kun oro e pe imo iwadii ijinle tawon se lo mu kawon se aseyori nipa ise ogbin iresi (rice) ti won poruko e ni ‘FUNAABA 1’ ati ti adie ti won poruko e ni ‘FUNAABA Alpha’, eyi ti won si n foju sona fun ijoba apapo lati lati wa a bu owo lu, ko si je ko po jaburata fawon eeyan lati je anfaani e.

Enikuomehin wa gboriyin fun igbese tuntun ti ijoba apapo sese gbe lati da FUNAAB pada si ileese to n ri sise agbe lorileede yi, iyen Federal Ministry of Agriculture and Water Resources lati maa sabojuto awon nnkan ti won n se.

Bee lo rawo ebe sijoba lati yan ajo kan to n ri soro ise agbe, iyen Agricultural University Coordinating  Agency (AUCA), ti won sese da sile lati rii daju pe won n se awon nnkan koriya fawon fasiti to n ri soro agbe lorileede yii.

Nigba to n kadi oro e nile pelu ayeye ikekoo gboye to n bo lona, o so pe awon akekoo 7,677 ti won se Full Time, awon akekoo 286 ti won se Part Time ni won maa gba iwe eri won lojo naa, nigba ti awon akekoo 1,442 ti won je akekoo post graduate atawon akekoo 203 ti won ni first class naa yoo gba iwe eri won bakan naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI