Ko si ibeere meji tawon ololufe okan lara
awon agba ilumooka nidi ise sorosoro, Babatunde AbdulGafar Okunade tawon eeyan
mo si Omoba n beere, bi ko se pe ki lo de ti ko fi soro lori redio mo, sugbon
toun n naa n so fun won pe oun nikan lo ye, ki won loo fokan bale.
Omoba Okunade |
Ohun ta a gbo ni pe ibeere tawon to gbo nipa
akoile eto ti Omoba to feran lati maa n gbe esin Islam laruge n beere ni pe ki
lo o de to fi je pe esin igbagbo lo tun fe e maa gbe laruge sugbon ta a pada
gbo pe esin Kristeni ati Islam lokunrin naa n se bayii latari awon iwadii
ijinle to n se nipa esin.
Idi ni pe akole eto ti won ni Omoba fe e bere
ni ose to m bo yi lo pe ni “Lati
Inu Iwe Mimo Lori Paramount FM”, to si ti pari gbogbo awon nnkan to ye lati je ki eto naa te awon ololufe e lorun.
AWIKONKO gbo pe aago mokanla aabo aaro ni
gbogbo ojo Abameta Satide ni eto naa yoo maa waye, ati pe ojo kokanlelogun,
iyen ojo Abameta Satide to m bo yi ni akoko eto naa yoo bere nibi ti yoo ti maa
foro Olorun bo awon eeyan.
Bakan naa la gbo pe yoo maa beere ibeere lowo
awon to ba n gbo o, ti yoo si tun fi anfaani sile fawon eeyan lati beere
ibeere, ti yoo si da won lohun lona to ye.
Nigba to
n jerii si, Alaga egbe sorosoro nipinle Ogun, Komureedi Olufemi Iyanda Omilani
so pe lati le mu ileri toun se fawon omo egbe lasiko ipolongo idibo ti won fi gbe oun wole gege bi alaga lo je koun loo sepade alaafia po peluu awon alase
ileese redio naa, ti won fun egbe won ni aaye lati maa seto nibe.
O ni
leyin ipade naa ni won fawon silooti merinla (14 slots), toun si fawon omo egbe
won lati maa seto lori redio naa, eyi ti Omoba funra e wa lara won, gege bi eni
to ti bo sori afefe tipe.
Fawon to ba mo ileese redio Paramount FM to wa niluu Abeokuta yi daadaa, won yoo mo pe ileese redio naa
tan kaakiri ile Yoruba, eyi ti yoo fawon to ba fe e polowo oja won lori eto naa
lati je kawon eeyan tete mo nipa oniruuru oja tabi okoowo ti won ba n se.
Fun alaye lekunrere tabi ibeere, yala e fe e
se ipolowo ni tabi e fe e gbe eto naa laruge, e le pe Omoba Babatunde Okunade
funra e sori nomba e, iyen 08032370756.
E ku ojulona eto tuntun “Lat’Inu Iwe Mimo
lori Paramount FM 94.5.
No comments:
Post a Comment