Gbajumo
olorin Fuji nni, Alaaji Ramoni Akanni tawon eeyan mo si RK1 ti so pe Olodumare
lo gbe oun leke, kii soogun nitori pe nigba toun maa bere ise orin lodun 1982,
oogun lo po tawon eeyan n se nigba naa latari ifigagbaga to po.
Ramoni Akanni |
Alaaji
Akanni ti won tun n pe ni Mista Lecturer to filuu e, Ogbomoso sebugbe lo
soro yi lakoko to n b’AWIKONKO soro nibi ayeye odun marundinlogoji to se ninu
gbongan ayeye Havila to wa lopopona ileewe girama tiluu Ogbomoso lojo Aiku
Sande to koja yii nibi ti won tun ti lo anfaani e se ifilole iwe tuntun to so
nipa igbesi aye e, ti won pe ni Mista
Lecturer, ti won si tun ti si boosi nla Toyota
Coaster.
O so
pe omodun merinla loun wa nigba toun bere ise orin Fuji to si je iyalenu fopo
awon eeyan pe omo kekere naa n korin. O lopolopo adojuko loun ba pade lenu ise
naa lati odun
Mista Lecturer so pe ise orin Fuji ti gberejige ju igba toun bere lo
latari awon olaju ati idagbasoke to ti wole to won wa nitori pe gbogbo nnkan
tawon fi n se nigba naa ni o ti di afiseyin ti eegun alare n fiso nitori pe
ohun gbogbo lo ti yi pada.
Nigba to n soro nipa adojuko, o loun ko le ka
adojuko toun ti ba de lenu ise yi tan nitori pe ko si ise ti ko ni adojuko,
sugbon ti ise orin Fuji yato gedengbe sawon to ku nitori pe ifigagbaga lo po
ju.
O so pe igba min in wa toun maa lo korin ofe,
ti won a tun so pe ki loun ko, a laimoye igba ti won ti fe e pa oun danu to je
pe Olorun lo ko oun yo.
Nigba to n daruko awon eeyan pataki to tiluu
Ogbomoso jade, Ramoni so pe lara awon gbajumo to jade lati Ogbomoso ni Baba
Oludare Foyenmu, 9ice to n korin, Oloye Lere Paimo, Okunnu, Femi Oladiti toun
naa n se tiata, Otolo atawon min in.
Ninu oro e, o so pe “Inu mi dun fun ayeye eto
odun marundinlogoji ti mo se yii, nitori ti eeyan ba ti n ba ise bo lati eyin
wa, to si ni alubarika, ko se daadaa nibe ni, ko si ri ope da. Olorun tun oore
min in ti a tun n dunnu si.”
Nigba to n soro nipa iwe to so nipa itan
igbesi aye e, ti won se ifilole e, o so pe “Onkowe kan lo ko iwe yii jade, o
jokoo, o si ronu wi pe ninu gbogbo olorin to jade lati Ogbomoso, ti won ti
korin paapaa ki won to o bi mi, o waa wo itan temi wi pe o da yato, eni to si
le ba ko wopo.
“O rii pe itan pataki ni itan mi, eyi lo fa a
to fi ko iwe naa jade, ati pe emi gan an o tete mo nipa e. Lara awon gbajumo to
jade lati Ogbomoso ni Baba Oludare Foyenmu, 9ice to n korin, Oloye Lere Paimo, Okunnu,
Femi Oladiti toun naa n se tiata, Otolo atawon min in.
“Igba ti mo bere, igba to lewu ni nitori pe
ifigagbaga po, eeyan si ni lati maa soogun lati maa fi daabo bo ara e, sugbon a
dupe lowo Olorun pe gbogbo e ti di irorun bayii.”
Lara
awon to wa nibi ayeye lojo naa ni Oba Dikita Munirudeen Adekola Lawal, Timi
tiluu Ede; Oba Mufutau, Onipe tiluu Ipe nipinle Kwara; Oba James Oyetunji Ojo,
Onipaki ti Soun Ogbomoso soju fun, Elekuro tiluu Ekuro.
Awon
min in ni Alaaji Wasiu Ayinde Merenge, Ogbeni Femi Ogunlana to so itan inu iwe
naa, Alaaji Yinusa Akanni, Alhaja Ganiyat Garba; Alaaji Taye Currency; Alaaji Bukola Alayande, Ere
Asalatu, Alaaji Lateef Goro atawon min in.
No comments:
Post a Comment