Gomina
ana nipinle Ogun ati oludije fun ipo alaga egbe oselu PDP, Otunba Gbenga Daniel
ti gboriyin fawon agbaboolu orileede Naijiria, Super Eagles fun akitiyan won
lati rii pe won lo fun idije ife eye agbaye to maa waye lodun to m bo, iyen
Russia 2018.
Daniel
fi idunnu e han leyin tawon ti Super Eagles fagba han akegbe won lati orileede
Zambia pelu aami ayo kan si odo niluu Calabar lopin ose to koja.
Ninu
iwe ti oludamoran pataki e, Ogbeni Ayo Giwa fi sowo s'Awikonko lo ti so pe inu
oun dun fun bi egbe Agba boolu naa se yege lati lo sorileede Russia nibi idije
ife agbaye.
Bee
lo tun gba won lamoran pe ki won tubo gbe ogo orileede Naijiria yo nibi idije
naa lati rii daju pe won gba Ife eye naa wa sile.
Daniel
to tun je gege bi baba Isale, iyen Grand Patron fun egbe Sports Writers'
Association of Nigeria so pe oun yoo tubo maa sagbateru ere idaraya lorileeede
nigbakugba ti aaye e ba si sile foun nitori nnkan toun nife si julo ni ere
boolu.
No comments:
Post a Comment