Oba Oniro fee sayeye odun keta lori ite - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 13, 2017

Oba Oniro fee sayeye odun keta lori ite

Gbogbo eto lo ti fe e pari bayii fun ti ayeye odun keta lori ite ti Oba Najeem Alani Eyiowuawi Aromaye Adebari, Oniro tiluu Iro, Igbeyin niluu Egba nijoba ibile Obafemi Owode nipinle Ogun.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo l’Ojobo Tosde to koja yii ni won ti so pe ojo Aiku Sande, ojo kejila osu kokanla to n bo ni ayeye naa yoo waye niluu Iro nibi ti awon eeyan jankan-jankan to fi mo gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun yoo ti wa ye gbogbo omo ilu Iro sii.

Lara awon ti yoo tun wa nibi ayeye lojo naa ni Komisana foro asa ati ise, Basorun Muyiwa Oladipo; komisana foro oye jije, Dokita Babajide Ojuko atawon min in to nife Oba Najeem Aromaye atawon omo ilu Iro.

AWIKONKO gbo pe orisirisi eto olokan-o-jokan ni won ti la kale lati mu ayeye odun keta naa dun, eyi ti won so pe ojo Eti Fraide, iyen ojo kewaa osu kokanla ni Kabiyesi atawon oloye yoo loo kirun Jimo ni Mosalasi tiluu Iro, iyen Iro Central Mosque.

Ojo Abameta Satide to tele la gbo pe Ere Faaji yoo waye fawon omo ilu Iro atawon oloye ilu naa nibi ti won yoo ti forin, ilu atawon nnkan asa dawon eeyan atawon alejo laraya, ko too di pe won yoo pari eto naa lojo Aiku Sande, ojo kejila gege bi won ti se la a kale.

Ojo naa yoo larinrin ju oju tawon eeyan yoo fi wo o nitori bi won se so pe ona ara oto ni won fe e gba sayeye naa, eyi ti won so iru e ko tii waye rii niluu naa latari awon idagbasoke ti o lafiwe to ti de ba ilu naa latigba ti won ti yan Oba Najeem Adebari gege bi Kabiyesi.

Opo awon Oba alaye nipinle Ogun ati agbegbe e ni won ti n mura sile fojo naa lati ba Oba Najeem yo ayo oriire naa, ti won yoo si tun ki awon omo ilu Iro ku oriire ti Oba ti Olodumare yan fun won.

Won ti wa a fi anfaani ayeye odun keta Oba Najeem yi ke si awon omo bibi ilu Iro to ti rin irin ajo lo sawon orileede kaakiri agbaye pe ki won maa bo wa sile lati waa foju won to awon idagbasoke alaragbayida to ti de ba ilu won.

Bee ba gbagbe lai pe lawon odo niluu Iro labe asiya National Association of Nigerian Youths (NANY) gboriyin fun Oba Najeem gege bi eni to nife awon araalu, paapaa awon odo, nitori pe o n ko won mora, ko si foro eleyameya se laarin ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI