Adura to ye ki a maa tete se Amin si ni
ti won ba n gbadura pe ki eeyan ma rin arinfese si, tabi ki eeyan ma rin lojo
ti ebi n pa ona, nitori eyi lo nibamu pelu bi Tanka ileepo kan ti a ko tii mo
oruko e titi dasiko ta a sakojopo iroyin yin tan se te okunrin kan pa lori
okada lose to koja.
Oku e re nile |
Gege b’AWIKONKO se gbo, ni nnkan bii
aago mejo aabo asale ojo Monde to koja nijamba buruku naa waye niwaju ile ounje
igbalode kan ta a foruko bo lasiri, to wa ni adojuko Tarmac ti won ti n ta
foonu lagbegbe Ibara niluu Abeokuta nisele ti waye.
Ohun ta a gbo ni pe ina kan to maa n da
awon moto duro to lo da awon moto duro lale ojo naa, sugbon ti won so pe awako
to wa tanka epo naa ko duro, nitori ti ona e ko gba ibi ti awon moto toku n lo,
ti ina naa tori e da won duro.
Lara awon to ta AWIKONKO lolobo je ko
di mimo pe olokada to n bo leyin tanka epo naa ni ko tete fura wi pe tanka epo
yi ko duro, ko too di pe o fe e lo ona eburu lati sare koja legbe e, sugbon ti
ori tako o lale ojo naa.
A gbo pe pe olokada naa se de egbe
tanka yi lati sare koja legbe e, abe taya iwaju lo ko si, toun ati eni to gbe
si subu sii labe, ko too di pe taya e to wa leyin te eni to gbe seyin pa,
sugbon ti ori ko oun yo.
Won ni esekese ni okunrin ti olokada
naa gbe seyin ti ta teru nipa nitori ti taya tanka epo naa te ori e fo si wewe,
ti opolo e si fo jade sita.
Awon tisele naa soju won la gbo pe won
tete da awako tanka naa duro pe o ti pa eeyan, sugbon ti won so pe ariwo to gbo
lo je ko duro lati mo nnkan to sele.
Eya ara e |
AWIKONKO gbo pe ko seni to mo bi awako
tanka epo naa se rin in nigba to bo sile lati mo nnkan to sele, to si rii pe
oun ti pa eeyan, bee naa ni won so pe olokada ti ori ko yo naa na papa bora, ti
ko seni to le so bo se rin in.
Won lesekese lawon tisele naa soju won
ti ranse sawon ajo to n dari oko lopopona nipinle Ogun, iyen ajo TRACE, ti won
si palemo oku naa lo si mosuari osibitu ijoba to wa ni Ijaye.
Lati fidi isele naa mule, Ogbeni
Babatunde Akinbiyi b’AWIKONKO soro lori foonu laaro ojo keji, oun lo si je ko
ye wa pe lesekese tawon ti gbo lawon ti sare lo, tawon si ti gboku naa lo si
mosuari to wa n’Ijaye.
Akinbiyi
so pe iwadii si n lo lowo lati mo ileepo to ni tanka epo yi ati olokada to salo
naa toun yoo si fi to wa leti bi nnkan ba se n lo si, sugbon ti a ko tii gbo
nnkankan titi dasiko ta a sokojopo iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment