Bo tile je pe awon olopaa si n se
iwadii labele lowo, sibe iyalenu nisele buruku naa si n je fawon fawon ara
agbegbe Isale Oko niluu Sagamu, ipinle Ogun lori bi awon adigunjale se pa baba
agbalagba eni odun mejidinlaadorun (68), Bantefa Oyebanjo
Gege
b'AWIKONKO se gbo, oru ojo Satide mojumo Sande ni won so pe awon adigunjale loo
sileepo Oando ti Isale Oko naa, nibe ni won so pe Oyebanjo ti ba won woya ija
ko too di pe omi teyin wogbin lenu, ti won si se oloogbe naa nisekuse.
Adugbo
Itunla Quarters legbe Aafin Akarigbo tile Remo ni won so pe baba agbalagba
oloogbe naa n gbe pelu awon omo e atawon omo omo e, ti won lo ti doloogbe, iyen
Toyin.
Bo
tile je pe orisirisi aheso la gbo pe o fa a tawon adigunjale naa fi loo sile
epo naa, sugbon lara ohun taa gbo ni pe owo kan ti won so pe awon osise ileepo
naa pa lojo Satide ojo keje osu yi to le ni milionu meji lo han sawon
adigunjale naa, ti won fe e lo gbe.
Won
ni se lawon adigunjale naa tun gbe ero amunawa jenereto ati irinse ti won fi n
ge irin wa sibe loru ojo naa lati fi ge ilekun irin to wonu ofiisi ileepo naa.
AWIKONKO
gbo pe ibi ti Oyebanjo won loo ti le lodun marun in to ti n sise sikioriti
nileepo Oando naa lugo si lawon adigunjale naa ti won lawon olopaa si n wa won
wa, to ti n gburo pe awon kan n yo kelekele layika ileepo naa, to si seese ko
je pe ise ibi ni won fee wa se nibe.
Lesekese
ni won loo ti dide lati loo loju won, toro naa si di isu ata yan-an-yan laarin
won, ko too di pe won bere sii lu lalubami, ati pe nigba ti won so pe agbara
awon jagufa naa ko fee ka Oyebanjo je ki won pinu lati de lowo atese.
A
gbo pe gbogbo bi won se n fi ada sa Oyebanjo lara ni ko wole, eyi lo fa a ti
won fi so pe afi kawon rii daju pe awon gba emi e, ko too di pe won sa a, ti
won si gun un pa.
Ohun
taa gbo ni pe okan lara awon osise ileepo naa lo ri Oyebanjo nibi ti won pa a
si, ti won tun fi paali atawon aso kan bo o mo, to si ke gbajare sawon
araadugbo pe ki won gba oun.
Lesekese
ni won lawon ero ti pe jo lati loo wo nnkan to n sele, ko too di pe won ranse
sawon olopaa, ti won si gboku naa lo si mosuari OSUTH to wa leyin aafin Akarigbo
tile Remo.
Michael, aburo Bantefa |
Okan
lara awon ore Oyebanjo to ko lati daruko e so pe iku oro ni won fi pa oloogbe
naa, ati pe aini ibon lowo lo fun won laye je nitori pe oun mo ore toun ni, ko
nii gba fun won.
O
so pe bo tile je pe Bantefa ko nigbagbo ninu oogun ibile, eyi to fa ki ko fi ni
onde tabi gbekude ati gbetugbetu lara lo fa a ti won fi tete muu bale, nitori
pe oju lasan ko see sise ode, iyen sikioriti.
Lara
awon araadugbo Isale Oko ti won n sise nitosi ileepo naa, ti won ni ka foruko
bo awon lasiri to b'AWIKONKO soro so pe o seese ko je pe lara awon osise ileepo
naa lo fawon adigunjale naa lowo pe owo wa nile tawon ko gbe lo si banki, ki
won waa lo o gbe e.
Won
ni biku ile ko ba pani, tode o le pani lo mu kawon adigunjale naa gbe irinse
dani lati fi ja ilekun ofiisi ileepo naa, ti won tun so bi won se le mu
Bantefa to je sikioriti won bale lati gbemi e.
Sande
Sonuiki, ore oloogbe naa so pe odo oun ni Oyebanjo wa ko too di pe o lo sibise
lale Satide toun ko si fura pe ale ojo naa lawon yoo rira mo.
O
so pe nigba ti won pe awon tawon de be, oku e lawon ba nile, tawon tun ri bi
won se ge ilekun ileepo naa. O ni okan lara awon osise ileepo naa to koko de
laaro ojo naa lo pariwo sita.
Nigba
to n soro, Ogbeni Michael Adeniyi Bantefa to loun ni won bi tele oloogbe naa to
niluu Eko loun n gbe so pe ona soosi loun wa ki won too pe oun pe won ti pa
egbon oun, lesekese loun ti wo moto lati loo wo nnkan to n sele.
Michael
so pe bo tile je pe awon olopaa ti bere ise iwadii, sibe awon ti loo si kootu
lati loo se afidafit pe awon ko ba ileepo naa sejo, ki won si je kawon loo si
iku egbon oun ko ba maa rare ninu mosuari to wa.
O
lawon fee yanju oro naa labele ko ma di pe awon ma maa tun lo maa kawon poyin
ni kootu tabi lodo awon olopaa lose ose, kawon olopaa se nnkan to ba ye ki won
se.
Iya
agbalagba to.loun ni won bi ki won too bi oloogbe naa, Cecilia Oduwole nigba to
n fomije soro so pe ibanuje NLA ninu aburo oun je nigba ti won mu iroyin naa wa
foun.
A
gbo pe AJC World nipinle Eko, iyen ileese to n se ipara pomade ni oloogbe naa
ti sise, leyin to kuro nibe lo wa si Robber Plantation to wa niluu Sagamu nibi
to ti feyin ti. Nitori ko ma baa maa jokoo lasan lo fa a to fi loo gba ise
sikioriti.
Ohun
ta a gbo ni pe ojo Wesde ni won sinku baba naa nilana igbagbo leyin ti won so
pe won ti yanju oro naa laarin ileepo Oando atawon ebi.
Won
ni egberun mejila naira ni won n so fun baba naa, ati pe won seese bere sii San
owo naa fun un nigba ti eto oro aje orileede yi lo soke.
No comments:
Post a Comment