Okan
lara awon irawo to sese n dide bo nidi ise orin Islam, Hajia Sheidat Silifat Akanni (Omo
Iyawo Anobi) tawon eeyan mo si Ta L'Olohun ti so pe ko si isoro meji
toun n ni lasiko yi, bi kose ti ipenija maketa to n mu ifaseyin ba oun. O
so pe nigba toun maa gbe awo orin orin akoko oun jade lodun 2013,
maketa toun ri nigba naa lo mu ifaseyin ba orin naa, peluu bi awon eeyan
se feran orin naa to. Hajia Sheidat, akobi omo ilumooka olorin Fuji
nni, Alaaji Ramoni Akanna tawon eeyan tun mo si Mista Lecturer lo soro
yi lakoko to n b'AWIKONKO soro niluu Ogbomoso nibi ayeye odun
marundinlogoji ti baba e, Akanni ti n korin. E ka bi iforowero naa se lo sii.
TA L’OLOHUN: Oruko mi ni Sheidat
Silifat AbdulRahmon Akanni tawon eeyan mo si Tal’Olohun, omo bibi ilu Ogbomoso
ni mi
AWIKONKO: Bawo le se bere?
TA L’OLOHUN: Lati kekere ni mo ti ni
ebun orin kiko nitori pe olorin ni baba to bi mi lomo, Alaaji Ramon Akanni
tawon eeyan tun mo si Mista Lecturer, idi ni yii ti maa fi so pe ajogunba ni
ise orin ti mo n ko. Nnkan ti mo ri ni pe lati kekere ti mo ti wa nileewe, emi
ni mo maa n saaju awon egbe ta a jo n korin, igba ti baba mi si rii pe mo ni
ebun e, inu won dun gege bawon naa se n korin, won gba mi nimoran pe ki n ri
daju wi pe mo teju mo iwe mi, ki n si kawe yanju daadaa.
AWIKONKO: Awo orin meloo le
ti gbe jade?
TA L’OLOHUN: Awo orin kan soso ni mo si
gbe jade, Ta l’Olohun ni akole e, odun 2013 lo jade, sugbon nnkan ti ko je ki
orin naa ta daadaa ni maketa ti mo ri nigba naa. Oun lo da bi eni pe ko je ki
orin naa ta bo se ye. Adura mi ni pe ki Olohun je ka ri eeyan gidi ba dowo po.
AWIKONKO: Nje e tun ti n
pinu lati gbe awo orin miran jade leyin Ta L’Olohun?
TA L’OLOHUN: Nigba ti mo se Ta
L’Olohun, opo awon eeyan lo n beere pe iru orin wo leleyi, sugbon nigba ti won
gbo o, won rii pe orin to se e gbo ni. Ibeere lasan ni akole yen. A mo orin i
gbo ju ara wa lo. Ninu orin naa ni mo ti beere pe ta lo da Olohun mo, ta ni
Olohun, mo je ko ye awon eeyan pe o se koko ka da Olohun mo ti a ba so pe a n
sin Olohun. Nnkan to n dun mi ni pe ko tii rin de ibi ti mo fe ko rin de, lo fa
a ti mi o tii se fe e pinu lati se awo orin min in jade. Ipenija maketa lo fa a
ti ko fi rin bo se ko rin. Mo gbiyanju lati paaro maketa, eni ti mo tun ri
nigba naa, oun naa ko gbe orileede Naijiria, ko raaye fun mi. Sugbon mo
nigbagbo pe orin naa si maa rin nitori pe ko seni to gbo orin naa, ti ko ni kan
saara sii.
AWIKONKO: Ki lawon ipenija
tabi adajuko ti a ti ba pade?
TA L’OLOHUN: Looto, ipenija po, sugbon
mi o ri won gege bi ipenija. Eyi ti mo rii pe o dun mi ju, mo lo lokesan kan
niluu Ilorin, ti awon kan pe wa si, nigba ta a se tan, eni naa ko fun wa lowo
ise wa, o si dun emi atawon taa jo lo nitori pe gbogbo ara la fi sise naa. Fun
bi ojo meta ta a fi wa ninu oko abule to mu wa lo ni a o fi ri ounje je. Mo ni
lati gbe e kuro lara nitori pe mo sese n dide bo ni, mi o si gbodo wo owo ju
nitori pe lara awon amoran ti baba mi n fun mi niyen, ka le debi ta n lo. Ati
pe baba mi maa n royin awon nnkan toju won ti ri nidi ise yii, eyi lo je ki emi
naa gbe e kuro lokan pe bo pe, bo ya, o si maa da. Teeyan ba si ni amumora, o
maa jana lojo kan. Mi o ri ojo ti inu mi baje nidi ise yi, nitori pe ise ti mo
feran ni, nnkan to ba si wa, a fi ki n gba a.
AWIKONKO: Kini e fe e so
nipa imura awon obinrin olorin Musulumi?
TA L’OLOHUN: Looto imura opo awon
obinrin to n korin lasiko yi ko bojumu to. A o le tori i pe olaju ti wole de,
nnkan esin la n se, eeyan si gbodo maa mura bo se to ati bo se ye, nitori pe
iwa ati imura yen gan an lawon eeyan a fi maa wo wa pe a n ko won lekoo. Won si
gbodo ri eko ti a n ko won lara wa.
AWIKONKO: Nje e ti bawon
eeyan korin papo ri?
TA L’OLOHUN: Beeni, mo ti bawon gbajumo
olorin korin papo ri. Lara won ni Alaaji Taye Currency, Big Dadi; Alaaja Amina;
Dadi mi niluu Ilorin, Aburido. Lowolowo
bayii, mo tun n gbaradi fun kolabo peluu Ere Asalatu, ti mo si gbagbo pe o maa
yori si irorun.
AWIKONKO: Gege bi eni ni
baba e korin, nje baba yin maa n ri aaye lati ko o yin lorin?
TA L’OLOHUN: Awon kan ti beere iru
ibeere yi ri lowo mi. Nigba ti mo se awo orin Ta L’Olohun lodun 2013, opo awon
eeyan ni won so pe baba mi lo ko mi lorin. Ti m ba so fun un yin pe lati ojo ti
mo ti n lo yara igbohunsile (studio), baba mi ko tele mi lo ri, ko da a, wo ko
mo ibi ti mo ti n korin, won ko ko ri mi nibi ti mo ti n se igbaradi orin
(reheasar) ri. Sugbon baba mo pe mo ni ebun orin.
AWIKONKO: Ewo lo dara ju
ninu kolabo ati keeyan da se orin?
TA L’OLOHUN: Ni temi o, to ba je pe
eeyan ri maketa gidi, o dara keeyan da se orin jade, nitori pe eeyan maa mo
nnkan ti eeyan n se. Nnkan mi in le sele lati ibi ka maa se kolabo, awon min in
le bere sii maa fe ara won, ki won si maa wo orisirisi aso ti ko boju mu. Sibe,
kolabo naa dara pupo, nitori pe o maa n gbe opolopo awon olorin, paapaa awon to
sese n dide bo bii temi. A kan gbodo fi iberu Olohun se gbogbo nkan ti a ba n
se ni
AWIKONKO: Afojusun yin lojo
iwaju?
TA L’OLOHUN: Afojusun mi po nitori pe
mo ni nkan ti mo fe e se lojo iwaju. Won si maa n so pe ki a ma tori nkanti a
fe je, ka fi ba nkan ti a fe e je je. Eni to ba ni ojo iwaju to dara, o ma maa
ro bi ipinle ojo iwaju naa ko se nii baje, ko si ni fe e se nkan to maa ba
loruko je, nitori pe ibi to n lo si jin.
AWIKONKO: Ki ni amoran yin
fawon olorin to sese n dide bo bii ti yin?
TA L’OLOHUN: Imoran fawon asiwaju wa,
nitori pe mo ba orin nile ni, emi naa o tii le pe ara mi asiwaju, ohun ni pe ki
won se daadaa lati le je eko rere fawon to m bo leyin. Ka ma tori olaju to de
ba ara wa je, nitori ara wa ni a le ba je, a ko le ba esin je. Bi eeyan se duro
loto naa ni esin duro loto. Fun awon to m bo leyin, ki won ma kanju nitori baba
mi maa n so fun mi pe asiko onikaluku otooto ni, ki a ma kanju, igba eeyan ko
si nii koja onigba. Awon kan maa n so pe ki won wa feyin lele ti won ba fe
edabi lagbaja, iro ni won n pa. Awon gan an ni won a pada maa fi eeyan se yeye
teeyan ba di gbajumo lawujo.
TA L’OLOHUN: Ko da a, Olohun gbakoso
nitori pe awon ti a ko lero pe won le wa ni won dide wa. Eeyan o le so bi inu
enikan se dun to, on’inu lo le so nitori pe awon ta o lero pe won le fi
taratara ba wa se ni won fara sise fun wa lojo naa. Gbogbo eto lo si lo bo se
ye ko lo.
AWIKONKO: Ki ni e le so
nipa baba yin?
TA L’OLOHUN: ti m ba ni ki n maa menuba
oro nipa baba mi, ile a su, bee naa ni ile a tun mo. Onifuji ni baba mi, ti won
ko ba si sise Fuji, Aafa ni won ko ba se. Idi ni pe ti won ba soro, o maa ri be
e ni. Ti won ba si pe eeyan si akiyesi, keni naa gbo. Eni to ti ni iriri ninu
aye yi ni, Olohun si so iriri won di ola fun won. Mo si gbadura pe won a pe
laye je ounje omo. Ko si ibi ti baba mi le wa lorileede Naijiria yi ti won kii
wa sile wa a sun, ayafi to ba je pe won lo sere mojumo, won kii gbagbe ile.
Baba mi ko feran faaji repete, won maa n wa sile wa a sinmi.
No comments:
Post a Comment