Komisana
foro ilera nipinle Ogun, Dokita Babatunde Ipaye ti so sita gbangba pe ko si
nnkan to n je aarun ropa rose, iyen polio nipinle Ogun lasiko ta a wa yii,
nitori to ti di afiseyin ti eegun n fi aso.
Dokita Ipaye atawon igbimo ajo Rotary |
Dokita
Ipaye soro yi lakoko to n gba igbimo ajo kan to n ri si aarun ropa rose naa,
iyen Polio Plus Committee, Rotary International, District 9110 Nigeria lalejo
ni ofiisi e to wa ni Oke Mosan, Abeokuta lai pe yii.
O
so pe o ti to odun mejo bayii ti ipinle Ogun ti gburo nnkan to n je aarun ropa
rose naa nitori bawon se gbogun tii nigba naa, ti ko si tii si iroyin to jo mo
o titi dasiko yii.
Ipaye
fowo soya, o si seleri wipe ijoba ipinle Ogun n sise takuntakun lati rii pe
aarun naa jinna patapata sipinle Ogun ati agbegbe e, tawon ko si bii foju kan
oorun depodepo wipe awon yoo gba aarun naa laaye.
O
wa gboriyin fun ajo naa fun ipa ti won n ko lati rii pe alaafia awon araalu je
won logun, ati ifowosopo ti won ni pelu ipinle naa.
Ninu
oro ti e, alaga igbimo ajo naa, Dokita Bayo Windapo dupe gidigidi lowo ijoba
ipinle Ogun fun ifowosopo to ni pelu won ati bo se n gba won lalejo ni gbogbo
igba ti won ba ti wa.
Bee
lo seleri pe awon ko nii duro lati maa polongon awon nnkan to n dena aarun naa,
ati awon lati maa la awon araalu loye lori bi won se le gbe igbese aye alaafia.
No comments:
Post a Comment