Ko seni to
le ba mi loruko je
Bo tile je pe kii se nkan tawon eeyan n reti
lati gbo lenu Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun lo so jade sita lasiko ti won
reti lati gbo awon nnkan to tun fe e se lodun 2018 nibi ipade eto isuna, iyen
Town Hall meeting to waye ninu gbongan asa, Cultural Centre, to wa ni Kuto
niluu Abeokuta lojo Eti Fraide yii.
Sugbon se lo dabi eni pe Gomina Amosun mura
awon to n gbe iroyin buruku nipa e wa sibi ipade naa lojo naa, to sib ere sii
soro pe oun yoo ran awon eeyan lewon, ti ko si seni to le be oun, koun gbo sii
lenuu.
Gomina Amosun ninu oro e so pe “Igba kan, won
ni mo ti bi ibeji, wi pe mo ti fun odomobinrin agunbaniro kan loyun. Won a kan
maa ko ikokuko kaakiri. Eyin naa e woo, nigba teeyan lomo, to niyawo, ti won a
si lo maa ko iroyin iro sita. Sugbon sa o, emi ti pe awon omo mi o, mo so fun
won pe awon ni won n gbadura pe ka wole, a si ti wole, mo ti bawon soro
lorisirisi pe ki won sora won, ki won si mo omo eni ti won n se.
Won o kii se omode, gbogbo nkan ti won n ko
yii, awon naa ko rii ro. Boya le mo pe iya iyawo mi naa tun pe mi pe awon gbo
pe wipe mo ti bi ibeji, mo so fun won pe ibeji ke, ko ri be e, ki won ma si gbe
okan ara won soke lori iroyin ti ko lese nile.
Ti e ba n wa ibeji, odo iru awon alaaji egbon
mi ni ki e wa lo. Gbogbo iyawo to ye ki n ni ni baba ti ni nigba aye won. Iyawo
kan soso gan an, ijogbon ati wahala ni. Aaro yi ni mo de latilu Abuja ti mo lo,
ni bo ni maa ti wa raye iyawo min in.
Mo ti fe iyawo, odun merindinlogbon (26), o n
lo si odun metadinlogbon (27) bayii. Mi o niyawo kooro latigba ti mo ti fe
iyawo mi. Mo ti so fun won pe o digba ti m ba pe aadorin (70) odun ni maa to o
feyawo kekere. Iyawo kekere yi lo maa toju mi. Se e mo pe, emi atiyawo mi, agba
maa ti de nigba yen, a si maa nilo noosi to ma maa toju awa mejeeji.
E loo so fun awon to ba fe e se Gomina
nipinle Ogun, ki won loo jokoo bi a wa naa se n jokoo lati lo maa ronu nnkan ti
won ba fe e se fun ipinle won, kii se won lo maa ko orisirisi ikokuko kaakiri igboro.
Saaju akoko yi ni Gomina Amosun ti so pe oun
yoo ran awon to n ko ikokuko nipa e jade sita, lati fib a oun loruko, ati pe ko
seni to le ba oun loruko je, nitori toun ko ri awon iroyin naa ro rara, nitori
toun mo pe ise awon alatako ni, toun si mo won daadaa.
Ninu oro e lo ti so pe “Ko seni to le ba
Amosun loruko je tabi ki won da ijoba e ru o, mi o ti e ri awon nkan ti won n
ko, nitori pe ko kan mi rara. Won a kan maa ko orisirisi ikokuko. E je ki n fi
da yin loju, awon eleyi, won n lo sewon o, mo fi n da yin loju. (We are going to smoke them to serve as
deterrent, they will go to jail).
“Ewon ni won n lo, nitori naa ki eyin baba wa
Kabiyesi ma wa lati be mi rara nitori pe iru e ti sele ri. Mi o fe gbo wi pe
boya asise ni, won gbodo lo sewon ni, nitori pe won ye lati lo sewon.
“Bi eeyan ba ji, o ye ko ronu awon nkan to fe
e se fun ipinle Ogun lori bo se ma a dagbasoke, kii se pe ko wa lo o ko awon
kan ti won ko nise tabi ironu, ti won a loo jokoo sibi kan lati maa gbe opolo
lati ba n kan je kale.
“Idi ni yii ti mo maa so fawon ti ori won pe,
ti won n pe mi lati beere oro lowo mi pe ki won ma da won lohun, ki won seni
eni ti ko ri nkankan. Gbogbo won ni mo mo, ti mo si le daruko won.”
No comments:
Post a Comment