Ko seni to le di mi lowo lati dupo alaga PDP - OGD - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 11, 2017

Ko seni to le di mi lowo lati dupo alaga PDP - OGD

Gomina ana nipinle Ogun, Oloye Otunba Gbenga Daniel, OGD ti so o jade sita gbangba pe ko seni to le di oun lowo lati di ipo alaga egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP nile Yoruba (Southwest).

OGD soro yi lojo Aje Monde ijeta lati fi tako awuyewuye to n lo kaakiri orileede yii pe o see se ko so pe oun ko dupo naa mo lati fi aaye sile fun Oloye Olabode George to je igbakeji alaga egbe oselu naa tele.

Daniel so pe oun ko ni lero lati so pe boya oun ko nii dupo naa mo lati fi faye sile fenikeni, o ni iro to jinna si ooto oro ni nitori pe gbogbo nnkan loun fi kun oju osuwon lati di alaga egbe oselu alatako, PDP naa.

Daniel so pe bo tile je pe oun bowo fun Oloye Bode George gege bi agbalagba, to si je pe gbogbo awon tawon jo n le ipo naa lo je ore oun, sugbon oun ko le tori e so pe oun ko se mo nitori pe onikaluku lo ni ipinu e to fee se lokan.

O loun se iwadii daadaa, paapaa nibi ipade gbogboogbo egbe tawon se lai pe yi niluu Port Harcourt, toun ri bawon eeyan se nife oun to, toun tun mo awon agbaagba to se tan lati gbaruku ti oun.

Ninu oro e, o so pe "Gbogbo awon oludije fun ipo yi ni won je ore mi, sugbon gege bi e se mo mi pe mo maa n tun nkan se ni, ti mo si tun je eni to kun oju osuwon ju fun ipo naa.

" Mi o ni so pe mo fee pada seyin nitori pe mo se iwadi daadaa lakoko ipade gbogboogbo taa se niluu Port Harcourt, mo si mo awon agbaagbaa nile Yoruba to fe mi, ti won si setan lati fowosowopo pelu mi.

"Onikaluku lo ni erongba ti won lati dupo. Bawon kan se jade dupo lati fi kun oro ile aye won (CV), bee lawon kan n dupo lati fi ri nnkan gba, tawon kan si n dupo lati jawe olubori.

"Kii se oro boo-ba-o-pa. Oro oselu inu ile wa ni, eyi lo fa ti mo fi pinu lati jade dupo naa, ki n si gbegba oroke lati le lo iriri ati ogbon mi lati satunto egbe oselu yii."

Yato si Otunba Gbenga Daniel, lara awon min in to tun n foju sona lati di alaga egbe oselu PDP ni Ogbeni Jimi Agbaje lo dupo gomina ipinle Eko lodun 2015; Ojogbon Tunde Adeniran, minisita tele foro eto eko ati Ojogbon Toaheed Adedoja toun naa je minisita foro ere idaraya teleri lorileeede yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI