Ipinle Ogun naa nilo owo repete - Amosun rawo ebe si ajo NEMA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 20, 2017

Ipinle Ogun naa nilo owo repete - Amosun rawo ebe si ajo NEMA

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti rawo ebe sijoba apapo ati ajo to n ri si isele pajawiri, iyen National Emergency Management Agency (NEMA), lati je ki ipinle naa pelu awon ipinle ti yoo ma nipin ninu owo ti won n fun awon ipinle ti won n dojuko isoro omiyale ati agbara ya soobu (flooding).

Amosun soro yi nibi ipade eto isuna odun 2018 ti eka ileese ijoba to n ri soro isuna, iyen Ministry of Budget and Town Planning sagbateru e ninu gbongan asa, Cultural Center to wa ni Kuto, Abeokuta lonii ojo Eti Fraide, ogunjo osu kewaa.

Gomina so pe o ye kijoba apapo maa mo riri akitiyan tijoba ipinle Ogun n se lati maa daabobo emi ati dukia awon araalu latari bi won n sise losan ati loru, lati dena omiyale ati agbara ya soobu.

O ni ki ijoba oun too de lawon araalu ti n koju isoro omiyale naa, to si n gbe dukia awon araalu lo, sugbon tijoba toun gba opa ase lowo e ko ri nkan se sii.

Amosun tesiwaju pe nigba toun de lodun 2011, lara awon igbese toun koko gbe ni bi ko se ni si isoro omiyale naa mo, tawon eeyan yoo si maa sun pelu didi oju won mejeeji, paapaa lasiko ti ojo ba n ro.

O so pe kolonka lawon agbegbe tijoba ana ti ti pa, tawon eeyan ko si le fese rin koja nibe, depodepo wi pe won maa gbe moto won koja, sugbon ni bayii, gbogbo e lo ti di ohun igbagbe.

Bee lo tun so pe o ye kijoba apapo ati ajo NEMA wo akitiyan awon ipinle to n sise takuntakun lati dena iru awon isoro omiyale yii loorekoore, bii ti ipinle Ogun, ki won si je ki ipinle naa pelu awon ipinle to n je anfaani owo latodo ijoba apapo, ti yoo si je koriya fun won lati maa tesiwaju ise sii.

Amosun gboriyin fun ajo NEMA pelu bi won se n satileyin fawon araalu nipa fifun ijoba lowo lati maa fun awon ti won padanu dukia won sinu ijamba omiyale.

O wa fi kun oro e pe eto isuna odun 2018 tawon fe e yi lo maa je eyi tawon yoo ti sise takuntakun to je pe ijoba to n bo lodun 2019 ko nii nise pupo lati se, bi ko se pe ki won tesiwaju ninu ise tawon se ku.

Bakan naa lo menuba wipe eto isuna tawon yoo se gbeyin lodun 2018, iyen fun todun 2019, osu marun un pere lawon yoo se ninu e, to je pe ijoba to n bo lo maa tesiwaju e.

Amosun wa a rawo ebe sawon araalu wipe ki won loo fokanbale nitori pe gbogbo ise tawon n se, lawon yoo se lase pari kijoba oun to o gbe opa ase sile fun Gomina tuntun to n bo.


Saaju akoko yi Komisana feto isuna owo nipinle Ogun,Arabinrin Adesina Adenrele so pe ipade eto todun 2018 tawon se yi ni lati mo nnkan tawon araalu n fe, kijoba si le mo nnkan to kan lati se lodun to n bo, eyi ti yoo mu aye derun fun gbogbo eeyan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI