Okan
lara awon agbaagba to da ajo ojulalakanfinsoro, Fijilante sile lorileeede
Naijiria, Oloye Michael (Muftar) Ayinla Oke ti so pe ipa ti ajo naa n ko
lawujo, paapaa lorileeede yi ko kere rara nitori pe ise takuntakun ti n se lati
gbogun ti iwa odaran ko se e gboju fo da.
Oloye Ayinla Oke |
Oloye
Ayinla Oke lo soro yi lakoko to n gbawon oloye ninu egbe ajo Fijilante, iyen
Vigilante Group of Nigeria (VGN) lalejo niluu Abeokuta loni ojo Eti Fraide, ojo
ketadinlogbon (October 27, 2017).
Oloye
Oke to ti je alaga akoko fegbe Fijilante nipinle Ogun so pe ise naa tun ti fese
mule lasiko yi ju igba tawon bere e lo nitori pe awon to n dari e bayii ni won
ti mu olaju wonu e.
O
so pe awon eeyan lorileeede yi mo pe ajo Fijilante wa, ise ifira-eni jin
(voluntary) ni won se e, ti won ko si se e pelu ife inu won, nitori pe ko sigba
ti won ranse pe won, ti won kii dahun.
Nigba
to n gba ijoba lamoran, Oloye Oke so pe kijoba ipinle, paapaa ijoba apapo gba
ajo yi, ki won ran won lowo nipa owo, amoran ati adura nitori pe ise aabo ilu
ti won n se ko se e fenuso.
O
wa gbawon osise ajo naa lamoran wi pe ki won lo otito inu ati iwa omulaubi, ki
won ma si se agabagebe lati fi sise naa. Bee lo gba awon araalu naa lamoran wi
pe ki won fowosowopo pelu won nitori ise ti n se.
Ninu
oro ti e, olori ajo naa nipinle Ogun, Ogbeni Nureni Olanrewaju Adedoyin dupe
lowo Oloye Oke fun bo se gbawon lalejo, to si gbadura fun won pelu orisirisi
oro amoran.
Lakoko abewo naa |
Adedoyin
so pe ko si nkan meji to je kawon loo sabewo si Oloye Oke nile e, bi ko se owe
ti won maa n pa wi pe 'odo to ba gbagbe orisun e ma a gbe danu ni', tawon ko si
fe e parunparun nitori pe oun gan an ni alaga akoko fegbe naa nipinle Ogun.
O
ni baba awon ni, tawon si gbodo maa bowo fun un, nitori oun gan an nigi leyin
ogba to je ki egbe naa tubo fese mule nipinle Ogun, paapaa lorileeede Naijiria.
Bakan
naa lo rawo ebe sijoba ipinle ati apapo, awon araalu, paapaa awon to ni ileese
lati ran won lowo nipa owo, moto atawon nkan to le mu ki ise won rorun.
Bee
lo so pe adura ati amoran naa tun se koko nitori pe ko si beeyan se le rin ti ori
e ko nii min in.
No comments:
Post a Comment