Olori
ile igbimo asofin tuntun ti won sese yan nijoba ibile idagbasoke Ilugun, nipinle
Ogun, Onarebu Kolawole Akinsanya ti so pe ilosiwaju agbegbe oun paapaa ipinle
Ogun lo je oun logun.
Onarebu Akinsanya ati Onarebu Mofoluke |
Onarebu
Akinsanya soro naa lai pe yii nibi ayeye bura fawon oloye ile igbimo asofin
tuntun ti yoo maa sakoso ijoba ibile Ilugun ati agbegbe e ninu ogba ileese won.
Ninu
oro e lo ti so pe bo tile je pe oun ko figba kan ronu nipa pe oun yoo di olori
ile igbimo asofin nijoba idagbasoke naa, sugbon sibe, pelu ipinu toun ni lati mu
ijoba idagbasoke naa lo siwaju, oun yoo sa gbogbo ipa ati akitiyan yan oun lati
rii pe oun se nnkan tawon eeyan n fe lati odo oun.
Ninu
oro ti e, alaga ijoba idagbasoke Ilugun, eni to tun je alaga igbimo tuntun ti
won sese yan nile igbimo asofin naa, Diakoni Arabinrin Mofoluke Soremekun so pe
Onarebu Akinsanya kun oju osuwon lati dari ilu lo mu kawon pinu lati fa a kale.
O
wa gba Onarebu Akinsanya lamoran wi pe ko ma ri ara e gege bi eni to ti de ibi
to ye ko de, sugbon ko ri ipo naa gege bi ategun si ibi to si n lo lojo iwaju.
Leyin ayeye ibura naa |
Saaju
akoko yi AWIKONKO gbo pe pelu iwa irele, ife awon eeyan ti Onarebu Akinsanya
ni, lo je kawon eeyan paapaa awon araalu naa so pe oun lawon fe gege bi olori
won.
Lara
awon to tun wa nibi ayeye naa ni igbakeji alaga ijoba idagbasoke Ilugun,
Onarebu Joseph Kuyoro, Akowe ijoba idagbasoke Ilugun, to fi mo awon agbaagba
egbe oselu APC.
No comments:
Post a Comment